Bo tile
je pe agba osere tiata nni, Ogbeni Kayode Odumosu topo mo si Pa Kasumu so pe
oun ko fee fi toun yo awon omo orileede Naijiria lenu nipa ki kede sita gbangba
pe ki won ran oun lowo nipa aisan ti ko je koun gbadun lati nnkan bi odun meji
aabo seyin. Sugbon sibe okunrin naa si nilo owo repete ti yoo fi lo gba itoju
lorileede India.
Pa Kasumu |
Gbogbo
aye lo gbo nigba naa lohun. Isele yi lo gbe Pa Kasumu pada wa siluu Abeokuta
lati wa maa gbe ki won le mojumo daadaa.
Lojobo
Tosde ose to koja yi nigba to n bakoroyin soro lati ori ero alagbeka, GSM, lati
le mo nibo lo ku si, atipe bawo ni ti kaadi to n wa, Pa Kasumu so pe Olorun ti
lo awon alaanu kan foun lati gba kaadi irin ajo miran losu kokanla odun to
koja.
O so pe
bakanna lawon eleyinju aanu kan tun ti foun lowo, sugbon owo naa ko le gbe oun
lo sorileede India latinlo gba itoju nibe, o loun si nilo iranlowo owo si lati
odo awon eeyan.
Okunrin
naa ni itiju lo n je foun lati tun maa pariwo kaakiri ori redio, telifisan ati
iwe iroyin pe kawon omo Naijiria ran oun lowo nipa owo, leyin eyi ti won ti se
tele. O so pe koun ma da bi alaseju lo je koun dake bo tile je pe ara oun ko
tii ya.
Titi di
akoko ti a fi n koroyin yi, ileewosan ijopa apapo, Federal Medical Center, FMC
Abeokuta lokunrin naa wa bayii nibi to ti n gba itoju.
No comments:
Post a Comment