Asiri Faleye to n ko eru ole sile l'Abeokuta ti tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 21, 2017

Asiri Faleye to n ko eru ole sile l'Abeokuta ti tu o

Bi kii ba se opelope awon araadugbo ti won tete lo ta awon olopaa lolobo ni, boya Faleye Tosin, eni ogoji odun ko baa ti maa lu awon araadugbo naa ni jibiti bayii.

Tosin Faleye
AWIKONKO gbo pe lojo Eti Fraide to koja yi, ni adugbo kan ti won n pe ni Asaolu ni Ijemo nisele naa ti waye, nigba ti won so pe okan lara awon araadugbo naa lo so fawon olopaa to wa ni Oke Itoku pe ki won gba awon lowo okunrin to n fojoojumo ko awon eru kan tawon ko idi e wole.

Loju ese ni won so pe DPO ago olopaa naa ti ko awon olopaa e seyin lati loo foju ri okunrin naa, ki won si mo boya looto ni tabi iro.

Iyalenu lo je fun DPO naa, Ogbeni Doga nigba ti won loo wo inu ile Fakeye to si ri awon eru lorisirisi nibe, bi eni pe Show Room lo wo ni. Won lawon eru bii Radio, Telifisan, DVD, Fidio, Gaasi Idana, Paanu, awon waya ina atawon eru min in ni won ba nibe.

Lakoko naa ni won ni ori tako okan lara awon onibara e, Mukaila Ismail ti won lo n ta awon eru naa fun un, ki won too ko won lo tesan Oke Itoku naa lati sewadi bawon eru naa se je.

Oun to faa kawon araadugbo naa to loo foro naa to awon olopaa leti gege bi AWIKONKO se gbo ni pe, wo ni okunrin naa, iyen Fakeye kii se bee ko eru wole tele, sugbon iyalenu lo je fun won nigba ti won ri isowo tokunrin naa fi n ko awon eru naa wole.

Lara awon to gbe oro naa si AWIKONKO leti so pe, won ko fe ko digba tawon olopaa ba too wa ko awon araadugbo mo okunrin naa, lo je ki won tete pariwo sita, nitori pe aye ti gbege. Won lowo ounje lawon n wa, kii se owo olopaa tabi owo ejo.

AWIKONKO tun rii gbo pe ise awon to n toro baara lokunrin naa n se, ero jenereto marun, foonu olowo nla to to merindinlogbon, redio amohundungbemu ti won n gbe sinu ile (home theater) mokanla ni won tun ri gba lowo e.

Bakanna la tun gbo se lokunrin naa n toro baara kaakiri, to si n fi owo naa ya awon eeyan lowo ele.

Ogbeni Abimbola Oyeyemi to je agbenuso awon olopaa nipinle Ogun nigba to n jeri soro naa so pe, loju ese toun ti gbo nipa isele naa loun ti loo sabewo sibe, toun si rii pe looto ni.

Abimbola so pe, nigba tawon n beere oro lowo e, nnkan to so nipe oun gba awon eru naa lowo awon to n ya owo ele lowo oun ni. O lokunrin naa so pe ise ere idaraya awon to n gba eyin ori tabili, iyen Table Tennis loun n se.

Won ni Fakeye so pe odun 1995 loun ti bere sii sise naa, toun si n ri owo nidi e, ko too dip e oun bere sii ya awon eeyan lowo ele.

Agbenuso fawon olopaa gbawon eeyan lamoran pe ki won maa mo iru awon ti won ba n fun lowo daadaa ko too di pe won fun won lowo, nitori pe ayederu lo po ninu awon to n toro baara lasiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI