Ojo kokanlelogun osu keta layeye odun kewaa naa yoo bere o - Baba Ori Oke Solution - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2017

Ojo kokanlelogun osu keta layeye odun kewaa naa yoo bere o - Baba Ori Oke Solution


Wooli iranse Olorun nni, ti Olorun n lo lasiko yii, iyen Wooli Jeremiah Okunlola topo mo si Baba Ori Oke ti so pe ayeye odun mewaa ijo naa ti won fee se ninu osu keta odun yii yoo bere lojo kokanlelogun, iyen lojo Isegun Tusde.

Baba Ori Oke Solution
Bo tile je pe ohun taa gbo tele ni pe, ojo Aje Monde, ogunjo osu keta layeye naa bere, sugbon Baba Ori Oke so pe ko ri bee.

Wooli Okunlola je ko di mimo lakoko to n waasu lojo Aiku Sande to koja yii, ninu soosi naa to wa ni Sam Ewang, Leme, Abeokuta.

Gege bi AWIKONKO se gbo, isoji olojo merin ni won maa fi bere ayeye naa, eyi ti yoo pari lojo Eti Fraide, ti won a si se idupe lojo Aiku Sannde to tele.

Bi eto ayeye naa too se lo niwonyi; Lojo Isegun Tusde ti won yoo bere, laarin aago mefa si meje aaro ni ipade adura; aago merin aabo irole si meje ni isoji ita gbangba. Bi won yoo si se see re fun ojo merin gbako.

Sugbon lojo Aiku Sannde ti won yoo kadi e pelu idupe aseyori ayeye naa, orin ilu ati ijo ni won fee fi se idupe, bo tile je pe adura ti won yoo gba lojo naa ko ju adura Ope lo, ni soki ni adura naa.

Lara awon olorin emi ti won n bo lati waa korin fun won lojo naa ni Ajihinrere Funmi Aragbaye, Ajihinrere Tope Alabi, awon Ayan Jesu atawon olorin emi miran.

Bakanna ni iranse Olorun Dayo Brown ko nii gbeyin lati fi ijinle oro Olorun lati inu bibeli bo awon eeyan lakoko naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI