AWIKONKO n ki Adejoke Ewa-Ede ku ayeye Ojo-Ibi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

AWIKONKO n ki Adejoke Ewa-Ede ku ayeye Ojo-Ibi

Oni je ojo malegbagbe ninu aye Arabinrin kan, to je okan lara awon asiwaju obinrin to feran lati maa gbe Asa ati Ede Yoruba laruge, Adejoke Sharon Somoye, topo mo si Adejoke Ewa Ede.


Bo tile je pe lati nnkan bi ojo meji seyin lomobinrin naa ti n fi awon aworan ara e sori ero ayelujara bii Facebook, Instagram, Twitter, Whatsapp lati fi ki ara e ku ayeye ojo ibi, paapaa lati fi dupe lowo Olorun fun ibi to wa lonii, sibe AWIKONKO ko nii fa seyin lati ki gbajugbaja sorosoro naa ku oriire ayeye ojo ibi e.

Bee ba gbagbe pe losu kokanla odun to koja ni Adejoke Ewa Ede se ayajo ayeye Ewa Ede olodoodun to ma n se lati fig be Asa ati Ede Yoruba laruge, nibi ti awon agbaagba leka Oselu, nidi ise ijoba, atawon ojogbon to mo nipa Ede Yoruba paapaa awon Asa ati Ise ile Adulawo ti peju sibe.

Bo tile je pe inu e ko fi bee dun si bi ayeye naa se lo lojo naa, nitori tawon Oba Alaye meji, iyen Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi ati Alake tile Egba, Oba Michael Aremu Gbadebo ti ko yoju ati awon eeyan jankan-jankan to ti fi iwe pe, sugbon ti won ko yoju lojo naa, sibe, o dupe lowo Olorun Aseda pe ipinu oun wa si imuse lojo naa.
 
Nibi ayeye naa ni Oba Orin, Saheed Osupa ti dalu bole fawon ololufee atawon alejo. Awon Obaye ko gbeyin nibi ayeye lojo naa.


Eni to ba ri Adejoke Ewa Ede, ko ba wa kii ku oriire ayeye ojo ibi e todun yii, ti a si n gba ladura pe, yoo se opo odun laye ati laaye rere ninu alaafia ati ifokanbale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI