E yo oro eleyameya kuro - Obasanjo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

E yo oro eleyameya kuro - Obasanjo

Balogun Owu to tun je Aare teleri lorileede yii, Oloye Olusegun Obasanjo ti gba awon omo orileede yi lamoran pe ki won maa wa ni isokan laifi ti eleyameya se toripe isokan lo ye wa ni Naijiria.

Obasanjo soro yii lakoko ayeye odun keresimesi to waye nilu Abeokuta lodun to koja.

O so pe bi awon elesin igbagbo ati musulumi ba te oro inu bibeli ati kurani, ko ni si n kan to n je eleyameya lorileede yi nitori pe esin ko ni won fi daa sile.

Bakanna lo tun so pe ki awon omo Naijiria maa ri daju ni gbogbo igba pe won n mu emi isokan lo laarin ara won. Awusa, Yibo ati Yoruba lo fimosokan lati gba orileede yi kuro lowo awon Oyinbo amunileru.

Bee lo tun so pe oselu tabi esin ko lo le yo wa kuro ninu wahala ti a ko ara wa si, bi ko se pe ki a fimo sokan, ki a si ni ife ati igbagbo to jinle ninu ara wa, ki ilosiwaju si le maa tesiwaju.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ninu oro tire, o ro awon omo orileede yi lati magbadura fun un ki o le kuro ninu wahala eto oro aje to ti dorikodo. O so pe ladura nikan lo le yo wa kuro ninu wahala naa.

Amosun so pe adura nikan lo ti n gbe orileede Naijiria ro latigba ti won ti gbominira. O wa ro awon adari kaakiri pe ki won tubo tepa mo ise won lona to ye.

Bee lo tun so pe bawon araalu ko ba dekun lati maa gbadura fun orileede Naijiria, ilosiwaju ati idagbasoke yoo tubo maa tesiwaju. Bakanna lo tun so pe ki won maa gbadura fawon asaaju orileede yi ki Olorun le tubo yi won lokan pada si rere.

Lara awon to wa nibi ayeye naa ni Aare fidihe teleri lorileede yii, Oloye Enerst Sonekan; Alakoso ati oludari ijo Redeemed Christian Church of God, Pasito Enoch Adeboye atiyawo e Arabinrin Folu Adeboye.

Awon miran ni Gomina teleri nipinle Ogun, Daniel Akintonde; Raji Rasaki, Rasheed Raji; Omowe Ebenezer Obey; Primate Peter Akinola; Primate ijo Aguda Methodist, Emeka Uche atawon mi in.

Lara awon to forin ati duuru dawon eeyan laraya lojo naa ni awon akorin egbe onigbagbo, CAN; Pasito Kunle Ajayi ti ijo RCCG; Gbajumo onkorin igbagbo nni, Tope Alabi, Ayan Jesu atawon mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI