Awon ajagungbale merin ti won seku pa obinrin kan ti wa lago Olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 20, 2017

Awon ajagungbale merin ti won seku pa obinrin kan ti wa lago Olopaa



L’Ojoru Wesde to koja yi lowo awon olopaa ipinle
ogun te awon ajagungbale merin ti won tun seku pa obinrin kan, Sidikatu Onasanya, eni odun mejidinlaadota lagbegbe Imoro ni Ogijo, nijoba ibile Sagamu.

Awon odaran naa
Gege bi AWIKONKO se gbo, lojoru Wesde ni omo obinrin naa, Wasiu Onasanya lo foro naa lo awon olopaa pea won ajagungbale kan ti pa iya oun. Adewale Abimbola, Monday Benzon, Mukaila Azeez ati Shodeinde Oluwafemi lawon ajagungbale towo te naa.
Ohun ti a tun gbo ni pe, inu oko ni Wasiu wa nigba tawon eeyan naa de lati wa jiigbe pelu awon eroja oloro ti won ko dani ni nnkan bi aago mesan ale. Nibi ti won ni won ti n fa oro naa, ni iya e ti yoju to si n bebe pe ki won ma gbee lo.

Lakoko naa ni won so pe okan lara won ti ti obinrin naa danu pe ko sun seyin fawon lo ti fidi janle, to si bere sii pariwo pe won ti pa oun. Ere ni won pee, a fi bi won se ni obinrin naa daku lo gbonrangandan, nibe lawon eeyan naa tin a papa bora.

Won ni se ni won bere sii fee lara, ko too soji saye, eyi lo mu ki won sare gbee lo si osibitu Mount Zion to wa ni Ikorodu, oju ona ni won lobinrin naa ti dake. Nigba ti won de osibitu naa lawon dokita so pe oku ni won gbe wa.

Bi Wasiu se kuro ni osibitu, ago olopaa lo gba lo, to si lo foro naa to DPO Ogijo Ogbeni Tijani Muhammed leti, tiyen si lewaju awon olopaa to lo koju won nibi ti won sa si.

AWIKONKO gbo pe, bawon eeyan naa se rii pe awon olopaa ti wa layika won ni won ti jade si won, ti won si doju ibon ko awon olopaa. Lesekese ni won lawon olopaa naa doku ija ko won. Igba ti won rii pe owo awon olopaa ti fee ka won lo mu ki won juwo sile lati salo.

Won so pe nibi tawon eeyan naa ti n salo ni ori ti tako awon merin, tawon toku si salo patapata. Bo tile je pe awon olopaa ko tii deyin leyin awon toku naa nitori ise iwadii ti won ni won n se lowo.

Alukoro olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri si isele naa so pe DPO to wa lago olopaa Ogijo lo lewaju iko to lo doju ko awon odaran naa. O so pe lesekese ni Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti so pe ki won maa ko won bo ni Eleweran lati tesiwaju ninu ise iwadi won.

Abimbola so pe bo tile je pe won ti gbe oku obinrin naa lo si motuari OSUTH fun ayewo iku to pa obinrin naa, Komisana ti dari ejo naa lo sodo awon FSARS lati tesiwaju ninu iwadi won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI