Won ni Pasuma naa ti n dari Fiimu bayi o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 20, 2017

Won ni Pasuma naa ti n dari Fiimu bayi oIbeere tawon eeyan n beere lowo ara won nigboro lakoko yi ni pe 'igba wo ni Oga nla Fuji, Wasiu Alabi Pasuma bere ise tiata toun naa ti wa deni to n dari fiimu agbelewo?'.

Ohun to fa Ibeere yi ko seyin ti fiimu kan ti won fee se ifilole e lojo karun osu to n bo ni gbongan Townsquare to wa lagbegbe Ajao, Ikeja nipinle Ekoo.

AWIKONKO gbo pe ALAGBEDE ni won pe akole fiimu naa ti won so pe Oga nla Fuji lo dari e lati ibere dopin. Iyalenu lo n je fawon osere tiata fun ti idagbasoke to de agba onkorin naa nidi ise tiata.

Gege bi a tun se gbo, won so pe Pasuma lo kopa ninu awon to ko fiimu naa. Bee la tun gbo pe titi ti won fi ya fiimu naa tan loro naa n se awon eeyan to wa nibe lakoko naa ni kayeefi nitori pe ko seni to gba pe okunrin to je pe ise orin ni Olorun yan mo lati orun wa naa se se daadaa ni lokesan naa.

Ibeere ti won so pe won beere lowo Pasuma ki won to bere lokesan naa ni pe 'se o daa loju pe o le dari fiimu naa tabi ki won gba elomin in?', sugbon ti won lo so pe ko ni sewu.

Gbogbo awon ti won ni won gba fiimu naa yewo ni won n kan sara si Pasuma fun ipa to ko naa. Won ni oriire nla ati ilosiwaju ni fiimu naa fa wa sinu aye e nitori pe kii se orin nikan lo moo ko mo bayii.

Bakanna la tun gbo pe inu yara ileese e ti won ti n po orin papo, ni won ti pari ise fiimu naa ti yoo si agbelewo lati osu to m bo.

Bakanna ni AWIKONKO tun gbo pe lokesan fiimu kan ti won pe ni Ijaya, eyi ti won bere lojobo Tosde ose to koja ni Pasuma wa pelu Ayo Adesanya, to si je awon mejeeji ni won fee kopa to poju nibe.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI