Buhari ti lo gba itoju ni UK o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 20, 2017

Buhari ti lo gba itoju ni UK o


Buhari lakoko to n wo oko baluu

Aare orileede Naijiria, Ogagun Muhammed Buhari lojobo Tosde ana ti kuro lorileede yii lati lo gba itoju to peye ni orileede United Kingdom, iyen ti won so pe isinmi olojo die ni Baba lo fun un.

Be o ba gbagbe pe laipe yi ni Buhari so pe, o ye kawon senato atawon oloriile igbimo asofin agba lo fun isinmi olojo mewaa lati lo gba itoju, ki won si le ni ilera pipe lati maa fi sise ti won yan won fun.

Ninu atejade ti Akowe agba e, Ogbeni Femi Adesina fi sita lo ti so pe isinmi olojo rampe ni Aare Buhari lo fun, lati se ayewo ilera ara e.

O so pe, bo tile je pe ojo Aje Monde ose to m bo ni won maa bere sii ka ojo fun Aare, ojo kefa osu to m bo ni Buhari maa pada sorileede Naijiria lati le tesiwaju ninu ise ilu.
AWIKONKO gbo pe, ki Aare Buhari to forileede sile lo ti fa ise le igbakeji e, Ojogbon Yemi Osinbajo lowo pe ko maa tuko orileede titi di asiko toun fi maa pada de sorileede lati tesiwaju ise oun.

Bo tile je pe orileede Switzerland ni igbakeji naa wa nibi to ti n lewaju awon iko tijoba apapo yan nibi eto oro aje orileede lagbaye, oni ojo Eti Fraide ni AWIKONKO gbo pe Osinbajo maa de sorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI