Olorun lo ko wa yo lowo Ogun aye lodun to koja - Ojogbon Oyewole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

Olorun lo ko wa yo lowo Ogun aye lodun to koja - Ojogbon Oyewole

Oga agba fun ileeko giga Ogbin nilu Abeokuta, Federal University of Agriculture, Ojogbon Olusola Oyewole so pe Olorun nikan lo gbe awon leke isoro tawon koju nileeko naa lodun to koja.
Ojogbon Oyewole

Ojogbon Oyewole soro yi nibi akanse adura lati fi wonu odun tuntun nileeko naa. Nibe lo ti so pe looto lawon la ogun ina koja eyi to ye ko mu ki ina ileeko naa to n jo, jo ajo reyin sugbon ti Olorun oga Ogo ko won yo.

O so pe o loju ileeko to le koju isoro tawon koju nileeko naa ki ileeko naa ma ti kogba wole tabi ki won si wa nibi ti won ti n ra koro lati dide pada, ki won si maa ba ise won lo bii ti tele, sugbon oore ofe Olorun lo gbe won leke, to si gbe awon duro.

Oyewole ro awon osise ileeko naa pe ki won maa dupe lowo Olorun ni gbogbo igba fun aanu ati oore ofe ti won ri gba. Bee lo ro awon agbaagba ileeko naa pe ki won fowosowopo pelu ife ati isokan lati le tubo gbe ogo oruko ileewe naa ga ju ti tele lo.

Oga agba naa fi aidunnu e han lori adojuko ti won koju, eyi ti ko fun won ni anfaani lati sise iwadi to ye ki won se, eyi tawon Ojogbon leka ogbin fowo si pe ki won se.

Bakanna lo so pe opin ti de ba gbogbo isoro ati ipenija tawon koju, ise ileeko naa yoo si pada maa lo bii ti tele.

O wa lo akoko naa lati fi dupe lowo awon osise, atawon oga leka-ojeka fun aduro tii won lodun to koja. Bakanna lo dupe gidigidi lowo awon akekoo fun bi won ko je ki mimi naa mi won, ti won duro pelu ogbon, imo ati oye.

Ninu oro ti e, Ojogbon Jacob Akinyemi to je alakoso eka ikeko nipa imo ero, iyen College of Engineering, (COLENG), O so pe Olorun nikan lo le se ohun titun ninu aye won lodun 2017 yii. O ro won pe ki won mo bi a ti n yin Olorun logo, ki won si maa gbadura fun ilosiwaju ileeko naa. Bakanna lp ro won pe ki won maa gbe igbe aye to mo, ti ko labawon.

Opo awon ojise Olorun ni won wa nibe lojo naa ti won si gbadura fun ilosiwaju ileeko naa, awon osise atawon akekoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI