Ko da, oro ibeere naa kii se aheso
oro rara, nitori pe ohun tawon eeyan fee mo gan an ni won n beere pe “nibo ni Iyalode Ile Yoruba, Oloye Alaba
Lawson wa?”
Iyalode Alaba Lawson |
Ko tii seni to sakiyesi obinrin to
sise takun-takun ninu saa akoko ijoba Amosun ati nibi idibo gomina ipinle Ogun
todun 2015, iyen lati rii pe Gomina Amosun pada sejoba eleekeji.
Latigba ti Gomina Amosun ti pada wole
eleekeji lobinrin naa ti n lewaju awon obinrin nibi awon ayeye tijoba n se,
atawon apejo ti won ba pea won oloselu si.
Sugbon, nnkan yi pada lojiji, bo se
je pe ko seni to gburo obinrin naa mo nipinle Ogun, paapaa lati soju ijoba nibi
awon ayeye to n waye. Eyi lo si faa kawon eeyan maa beere pe nibo lobinrin naa
wa.
Oloye Alaba Lawson to tun je alaga
igbimo fun ileeko giga gbogbonise Moshood Abiola to wa nilu Abeokuta, ti okan
lara awon omo e tun je okan lara awon komisana nipnle Ogun lawon eeyan ko gburo
e mo nipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment