Primate Udofia n sayeye ojo ibi lara-oto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2017

Primate Udofia n sayeye ojo ibi lara-oto


Primate Josiah Udofia
Idunnu subu-lu-ayo ninu ijo African Church lagbaye lori bi okan lara awon olori ijo naa lorileede Naijiria se n se ayeye ojo ibi e pelu eka ijo naa ti won tun n si sipinle Akwa Ibom loni Ojobo Tosde.

Gege bi AWIKONKO se gbo, Alagba, His Eminence Primate Emmanuel Josiah Udofia ni won so pe, oni Ojobo Tosde, ojo kerindinlogbon gan-gan ni ojo ibi e, ti won si n se lowolowo bi a ti n ko iroyin yi nipinle Akwa-Ibom. Katidira (Cathedral) nla ni won so pe Olorun lo o lati ko.

Bo tile je pe, AWIKONKO ko tii mo ojo ori iranse Olorun naa, bee ni a o tii gbo nipa agbegbe ti won ko ijo tuntun naa si nipinle naa, sugbon ohun ti a gbo ni pe, iranse Olorun naa ti so pe oun ko le se ayeye ojo ibi todun yii lai je pe oun pari soosi Katidira nla toun n ko lowo.

Lara awon omo ijo African Church Solution Camp Ground nilu Abeokuta to gbe oro si AWIKONKO leti so pe, Baba Udofia je okan lara awon agba iranse Olorun lorileede Naijiria ti Olorun n lo lati yi itan aye awon eeyan pada si rere.

Bakanna la gbo pe, Primate Udofia ko see fowo ro ti seyin nigba ti a ba n so nipa awon iranse Olorun to n pase irorun ati alaafia saye awon eeyan nipa adura pelu oruko Jesu Kristi.

Bee la tun gbo pe awon Ojise Olorun ninu ijo naa lagbaye paapaa lorileede Naijiria, bii Wooli Jeremiah Okunlola to je oludari eka ijo naa to wa ni Sam Ewang Abeokuta lo lo silu Akwa Ibom lati lo ba Primate Udofia se ajoyo ayeye ojo ibi ati ijo katidira naa ti won n si lowo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI