Ileepo Rabeng jona l’Adigbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 26, 2017

Ileepo Rabeng jona l’Adigbe

Lakoko ti won n pa ina
Beeyan ba rin sasiko ti ileepo kan ti won pe ni Rabeng to wa lagbegbe Adigbe nilu Abeokuta ti jona, omi oju yoo jabo loju onitohun nigba tawon eeyan jona yanna-yanna nibi ijamba ina naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ileepo naa wa ni adojuko gbajumo olounje kan ti won n pe ni Iya Sunday l’Adigbe, ni nnkan bi aago kan aabo osan oni, Ojobo Tosde ni ijamba ina naa bere.

Bo tile je pe, titi bi a ti n ko iroyin ni a ko tii le so nnkan to fa ijamba ina naa, sugbon awon eeyan dagbere faye nibi isele ijamba ina naa.

AWIKONKO gbo pe, loju ese ti ina la nileepo Rabeng naa lawon eeyan to wa ladugbo naa ti ranse pea won pana-pana atawon olopaa, bee ni won ranse sawon Sifu-difensi atawon Fijilante lati wa daabobo emi ati dukia awon eeyan.

Won ni kawon eso alaabo too de, awon eeyan ti gbemi min nibe, bo tile je pe, a ko tii le so iye awon to ku nibi isele naa. Loju ese tawon Fijilante ti de ibi isele naa, ni won ti bere sii fi omi pa ina naa.
Awon Fijilante lo n pa ina

Bakanna la gbo pe awon alaanu to wa lagbegbe naa ranse sileese pajawiri nileewosan ijoba to wa ni Ijaye lati wag be oku awon tori tako nibi ijamba ina naa.
Ni bayii, ohun taa gbo nip e, won ti gbe awon oku naa lo si ile igbokusi, iyen motuari to wa ni osibitu ijoba to wa ni Ijaye, Abeokuta.


Lara awon to jona
AWIKONKO yoo te siwaju ninu ise iwadii lati mo nnkan to fa ijamba ina naa. Olorun a maa so wa o. Amin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI