Lati le fidi otito mule nipa rogbodiyan to n lo laarin ilu nipa awon eso
alaabo ojulalakanfinsori, iyen Fijilante meji, VSO ati VGN ti won ni won n
figagbaga nipinle Ogun, Komisana to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle
Ogun, Ogbeni Babajide Ojuko ti so pe VSO, Vigilante Service of Ogun state nikan
nijoba ipinle Ogun fowo si lati maa sise aabo ojulalakanfinsori nipinle naa.
Ojuko soro yi ninu atejade to fi sita lose to lo lohun pe looto lawon
eso alaabo kan wa ti won n je VGN, iyen Vigilante Group of Nigeria, sugbon
ijoba ipinle Ogun ko tewo gba won lati maa sise aabo laarin ilu.
O so pe, ijoba lo ni ase lati se nkan to ba fe laarin ilu, awon ni won
ni eto aabo lowo nitori naa lo se je pe awon nikan ni won le bu owo lu ajo to
ba fee lati maa sise aabo laarin ilu fun eto aabo to pe ati idagbasoke.
"VSO nikan nijoba ipinle Ogun mo gege bi ajo eso alaabo
ojulalakanfinsori lati maa daabo bo awon araalu fun alaafia ati isokan awon
eeyan. Ijoba lo si mo eni to le gbekele to ba di oro aabo nitori nnkan to gbege
ni."
Gege bi AWIKONKO se gbo, won lawon kan ti won pe ara won VGN n so pe
awon naa mo nipa eto aabo, sugbon ti won o gba ase lati odo ijoba ipinle Ogun
ni won n da wahala sile laarin ilu.
Sugbon Komisana so pe "A ti bu owo lu Vigilante Service of Ogun
state. Nitori naa, nipinle Ogun, VSO nikan la mo dele soko kii se VGN
rara."
Bakanna lori oro awon Fulani daran daran ti won fojoojumo da wahala
sile, Ojuko so pe oro naa koja agbara ijoba ipinle Ogun, o ni ijoba apapo
orileede yi lo lagbara lati soro lori e.
No comments:
Post a Comment