Ijoba ti bere sii gbogun ti awon ayederu Oba l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

Ijoba ti bere sii gbogun ti awon ayederu Oba l'Ogun

Laini fi igba kan bo okan ninu, laarin awon ipinle to ni Oba lorileede yii, ipinle Ogun nikan lo ni Oba to poju, ko da bi a ba awon Oba ipinle meta mi in po, won o tii to ti ipinle Ogun. Nu kukuru, Oba to to igba ati mokandinlaata, 249 lo wa nipinle Ogun gege bi akosile.
 
Eyi lo mu ki awon Oba kan maa wo ewu ete pe ko seni to le mu won.

Lose to koja ni Komisana to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun, Babajide Ojuko fi atejade sita pe ijoba ti se tan lati dide ogun sawon ayederu to n pe ara won ni Oba nipinle naa lori bo se so pe se ni won n si ipo naa lo.

Ojuko so pe, Oba kan soso nijoba ipinle Ogun si fi je latigba ti won ti de, yato si pe won n fi awon Oba ropo awon Oba to ba waja. "Oba igba o le okandinlaadota, 249 lo wa nipinle Ogun" gege bo se so.

"Yato si Oba kan soso ti ijoba fi je, ijoba ipinle Ogun ko tii fi Oba miran je latigba ti won ti de lodun 2011 titi di asiko yii. Awon Oba ti won n fun lopa ase, iropo awon Oba ti won n waja ni won n fi won se.

"Ona ti a fi n gba yan Oba laye atijo ti yato pata si bi a ti n yan oba lode oni nitori le abuku ti ba pelu bi awon ti a n yan naa se n si agbara lo. Eyi lo mu ki ijoba ipinle Ogun dide lati se awon atunse lori e, to si mu ki a maa fi awon eeyan to too tan, ti won ni ise to to won jeun sipo.

"Opo awon ti won n yan sipo tele lo je pe won ko ni ise ti won n se ni pato, awon ti won nise naa, ko to won jeun. Ti won ba wa depo Oba tan, ile onile won a maa lo ta lati fi jeun, lai je pe won ni ile tele. Eyi ni won si fi n da wahala sile laarin ilu ti won je Oba le lori.

"Opo awon Oba yi lo je pe, iwa jagidijagan ni won n hu tele ti won fi n jeun, opo won ti daran ri ki won too fi won joba. Sugbon ni bayii ijoba ti setan lati gbogun ti oru awon Oba bee. Ki a si ri owo ibaje won bale pataki." Ojuko lo so bee.

Bakanna lo tun so pe ipele meta ni Oba pin si, ipele akoko ni ti awon Oba alaye to je merin ni won, awon ni Awujale tile Ijebu, Alake tile Egba, Akarigbo tile Remo ati Olu tilu Ilaro. Ipele keji ni ti awon Oba keekeeke ti won wa labe awon Oba alaye. Ipele keta ni awon baale ti won wa labe awon Oba.


Komisana naa tun soro lori bi won se maa fiya je awon Oba ti won ba se, o so pe, "lakoko, a o gbodo da ipo Oba papo mo oselu. A ti n gbe igbese pe, Oba ti a ba fee yan lasiko yii, a gbodo koko lo wo awon akosile e boya o ti se oselu ri tabi awon iwa to n hu tele ki a to fi je Oba."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI