Iyalenu lo je fawon ero to waa woran ni ileejo giga kan to
fikale si Isabo, Abeokuta lojo aje Monde to koja yii, nigba ti won da ejo iku
fun okunrin kan ti won pe ni Kola Akanji, eni won fesun kan pe o ji okada gbe,
eyi losi mu kawon eeyan naa ka owo lori pariwo “Haaaaaaa”.
Gege bi AWIKONKO se gbo, odun ojo kerindinlogun, osu kejila
odun 2010 ni won so pe Kola ji okada naa gbe, to si tun gun eni to ni okada,
iyen Moses Fashola naa nigo lori. Agbegbe kan ti won pe Ijaka Isale, nijoba
ibile Yewa nisele naa ti waye.
Fashola nigba to n soro lojo naa so pe, oun gbe Kola atawon
ore e lagbegbe Ijaka Isale lo si Ishaga Olowu. O ni nigba tawon koja agbegbe
Onigbedu loun rii pe ina okada naa ku lojiji laimo pe okan lara awon toun gbe
lo pa ina okada oun.
“Leyin ti won pa ina okada mi ni won womi bole, ti won si
gun mi nigo lori, ko too di pe won gbe okada mi salo. Lesekese ni mo ti sare
dide lati le won mu. Okada kan to n bo lo gbemi lati le won mu, ki n le ri
okada mi gba pada.
“Awon ara abule lo ba mi pariwo le won, ko too di pe won ri
Kola mu, tawon meji toku si salo patapata. Loju ese ni mo tii lo fa le awon
olopaa Onigbedu lowo, ti mo si salaye fun won lori nnkan to sele.”
AWIKONKO tun gbo pe, bo tile je pe Kola ko jewo ibi tawon
meji toku n gbe, sugbon latigba naa lawon olopaa ti n baa se ejo.
Esun odaran ni won fi kan Kola ni kootu, eyi ti won loo lodi
si ofin orileede Naijiria todun 2014, eyi to si je pe idajo e la iku lo.
Adajo ileejo lojo naa, Ogbeni Abiodun Akinyemi so pe oun ko
le gbe idajo to so mo iwa odaran ti Kola hu lojo naa koja. O so pe leyin gbogbo
atotonu ati awijare pelu ise iwadii to foju han pe looto ni Kola hu iwa naa.
Ogbeni Abiodun so pe, ileejo paa lase lati yegi fun Kola
titi tie mi yoo fi jabo lare e, ti yoo si ki aye pe o digbo se.
No comments:
Post a Comment