MC NDA fee se ayeye odun efe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2017

MC NDA fee se ayeye odun efe


Boi kan bai, boya maanu de ni ka pee, to maa n saba se eto lori telifisan OGTV to wa niluu Abeokuta yen ni o, Nurudeen Adebule topo mo si MC NDA lo fee sayeye odun efe, eyi to pe ni 'My Hood Comedy Plus 2017'.

Gege bi a AWIKONKO se gbo, won lokunrin naa tun fee se ayeye ojo ibi e lojo naa. Ojo kokanla osu to n bo, iyen osu keji lo fee se, gbongan Machy Lounge to wa ni agbegbe Okesanya adugbo Kunle ni Papa Ajao Mushin ipinle Eko lo fee lo.

Oniruuru eto olokan-o-jokan ni won ti la sile fojo naa nitori pe aago meji osan ni yoo bere.

Iyalenu to wa nibe ni pe, won lokunrin naa so pe eni ti ko ba ti ra fila to ta legberun meji ataabo naira ko nii wole sinu gbongan naa nitori awon godogodo yoo ti wa lenu ona lati da won pada sibi ti won ti n bo.

AWIKONKO gbo pe, bo tile je pe DJ Tee-Smart lo maa forin orisirisi dawon alejo laraya, sibe, okan lara awon olorin nni, Sammy Tee naa a tun dalu bole, nigba ti MC Sugar ati Bishop yoo tuko eto naa gege bi MC.

Opo awon aderin-posonu lo maa gba maiki lojo naa  nitori pe, odun efe lojo naa fee je, tawon eeyan yoo si rerin subu lori aga ti won ba fi jokoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI