Yeeeeeepaaaaa: Sefiu Alao soro buruku si Atawewe loju agbo, O loun kii segbe awon oga e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

Yeeeeeepaaaaa: Sefiu Alao soro buruku si Atawewe loju agbo, O loun kii segbe awon oga e



Sefiu Alao
Ojo male gbagbe lojo ti gbajumo olorin Fuji nni Alaaji Sefiu Alao Adekunle Kandoso soko oro si okan lara awon irawo olorin Fuji nni, Alaaji Sule Adio topo mo on si Atawewe loju agbo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, nibi ayeye kan ti okan lara awon gbajumo nile Yoruba, Alaaji Garuba Owoeye ti si Oteeli e to ko si Atan Ota nipinle Ogun nisele naa ti waye. Ojo Isegun Tusde ose to koja, iyen ojo kewaa osu yii ni o.

Ohun to sele ni pe, Alaaji Sule Adio Atewewe ni Alaaji Owoeye pe lati wa korin nibi ayeye lojo naa, ko si forin dawon eeyan laraya. Alejo Pataki ni won pe Alaaji Sefiu Alao fun lojo naa. Beeni naa ni won pe Agba olorin Waka nni, Olori Salawa Abeni naa gege bi alejo pataki.

Wahala naa bere lakoko Atawewe n korin lowo, nigba naa ni won so pe Sefiu Alao wole si gbangan naa, bo se wole ni won ni Atawewe ti rii, sugbon ti won so pe Atawewe ko forin kii kaabo, se lo n korin e lo. Won lokunrin naa, Sefiu Alao ko wo be, se lo n ki awon to ba nibe ko too lo jokoo sori aga.
Atawewe

Gbogbo bi Sefiu Alao se jokoo fun bii ogun iseju ni won so pe Atawewe ko ti e ri ti Sefiu ro. Sugbon bi won se ni Salawa Abeni wole sinu gbangan lojo naa ni Atawewe ti bere sii forin kii ni mesan-mewaa, to yi orin e pada sorin “Waka”  nibe ni inu ti bi Sefiu Alao pe abuku nla ni Atawewe fi ka noun lojo naa.

AWIKONKO gbo pe, Egbe Sefiu Alao ni won ni Salawa Abeni tun lo jokoo si lojo naa, sibe se ni Atawewe se bi eni ti ko ri Sefiu Alao nibi to jokoo si, to sit un n forin ki Salawa Abeni lo. Won so pe bi Obinrin naa se jokoo ni Atawewe sokale lo kii, to si fogbon ki Sefiu Alao lori ijokoo, sugbon se lokunrin naa yipako si Atawewe. Iyalenu ni won loro naa je fun Salawa ko too beere pe ki lo sele laarin won, toun naa si salaye nnkan ti Atawewe se fun un.

Bi won se ni Salawa gboro naa lo ranse pe Atawewe pe ko pada wa ki Sefiu Alao bo ti to ati bo ti ye. Won lobinrin naa ni ko dabale be Sefiu nitori Sefiu Alao kii seni to le ri fin tabi ko fi iwosi lo, nibe ni won lawon eeyan ti bere sii sakiyesi awon meteeta.

Bakanna ni AWIKONKO tun gbo pe, Ko pe ni won pe Salawa Abeni pe koun naa wa darin Waka fawon alejo, lesekese ni Sefiu Alao ti dide lati lo naa obinrin naa lowo aganran. Ohun taa gbo nipe eyin Salawa Abeni ni Atawewe duro si lakoko ti Sefiu Alao n naa lowo, sugbon bo se na owo naa tan, lo ba ju beeli owo toku si Atawewe. Won ni ki owo naa to de odo e lo ti keyinsi pe owo naa kere foun.

Salawa Abeni
Bi won se ni Sefiu Alao gboro mo Atawewe lowo ni yen, to si lo jokoo. Ori ijokoo yi ni won ni Sefiu Alao ti n ronu nnkan to le se fun Atawewe, sugbon nigba ti won ni Olorun maa gbe ogo e yo ni Alaaji Owoeye so fawon eeyan pe ki won je ki Sefiu Alao korin, pe oun fee gbo oro orin lenu e.

Nibe lo ti pinu lati soro buruku si Atawewe loju agbo naa, eyi ti won so pe iru abuku bee ko kan Atawewe ri loju agbo latojo to ti n korin.

Won ni Sefiu so pe ko sora e nitori pe, Oun Sefiu Alao kii segbe e ni gbogbo ona. won lo ni, kii se pe tori oun kii gbe igbe aye afefeyeye bi awon olorin toku, ko tumo si pe oun ko ju won lo. Okunrin naa wa lo ogbon agba lati so pe oun yoo dariji Atawewe foun to se nitori pe omo Abeokuta kan naa loun ati e jo je.

Won loju ti Atawewe lojo naa debi pe se lese e mejeeji n gba ara won lori ijokoo to jokoo si titi ti Sefiu Alao fi korin tan lojo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI