Kii se akoko ree tawon ajo to awon
oniroyin lorileede Naijiria, Nigerian Union of Journalist, NUJ maa so pea won
fee gbe awon ileese iroyin kan lo sile ejo lori ai san owo osu fawon osise won,
eyi to si n fa ifaseyin fawon eeyan naa.
Alaga ajo naa nipinle Ekoo, Ogbeni
Deji Elumoye lojo Isegun Tusde ose to koja ti so pea won ti setan lati gbe awon
ileese iroyin kan sile ejo latari ai ri owo osu san fawon oniroyin won, pelu
ise ti won n se fun won.
O so pe opo igba lawon ti fi leta
sowo si won pe ki won foju aanu wo awon osise ti won sise fun won loju mejeeji
lati ma je ki ileese won parun, ki won san owo osu fun won lasiko.
Elumoye so pe, bo tile je pea won
ileese iroyin die ti won gba leta naa ka ni won ti bere sii se daadaa fawon
oniroyin won ti won kawon ileese naa parun, sugbon awon toku sebi eni wipe won
ko ri iwe naa gba rara, eyi to si je ki won san owo osu fawon osise won titi di
asiko yii.
Elumoye nigba to n soro so pe, “Ai san
owo osu fawon oniroyin kii se ohun to bojumu, ao si gbodo foju food a tabi ka
fi owo yepere muu, ko see se. A ti n petu sawon ileese iroyin kookan, to si je
pea won kan ti n se dada. Awon toku ko tii se nnkan ti a fe, won ko tii tun
omoluabi won se.
“Nitori Olorun, bawo le se maa ko
lati san owo awon oniroyin ti won n lo kaakiri lati wa iroyin wa fun yin, ki
ileese iroyin yin ma baa parun. O ye wa pe awon kan n koju isoro owo gidigidi.
A si ti ba won soro lori ona ti won le gbee gba. Sugbon awon kan ko ni awijare
lati ma se san owo osu naa, ao si ni mu oro naa ni kekere pelu won.
“Paapaa, a ti fee pari igbese lati
gbe awon ileese iroyin nla meta kan lo sile ejo niwon igba ti iwe ipejo nab a
ti jale.” Elumoye lo soro bee.
Elumoye ro awon ileese naa pe ki won
rii pe won n san owo fawon osise won nitori wi pe inu didun lo n mu ori yiya
wa.
No comments:
Post a Comment