ABEOKUTA: Oluwo gbe Oba Agura lo sile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 23, 2017

ABEOKUTA: Oluwo gbe Oba Agura lo sile ejo

Oba Halidu Lakoko to je Agura tiluu Agbagura niluu Abeokuta ti n jejo lori esun ti Oluwo Adatan, iyen Oloye Mufutua Akinola pe pe kabiyesi ro oun loye gege bi Oluwo eyi to so pe ko ba ofin ati ilana mu.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO leti se so, ile ejo Majisireeti keje to wa ni Isabo niluu Abeokuta ni igbejo naa ti waye lose to koja nigba ti won so pe Adajo naa ti sun igbejo naa siwaju di ojo kefa osu kerin odun yii.

AWIKONKO gbo pe Adajo to n gbejo naa gege bo se so, o ni ojo naa loun yoo so boya igbejo naa yoo tesiwaju tabi fagile esun ti won fi pe kan Oba naa ati Oloye Nirudeen Olaleye ati Oloye Adenekan Jagunna.

Nitori bi agbejoro awon ti Oluwo fesun kan naa se bebe pe ki adajo maa je ki igbejo naa waye nitori ko lese nile.

Sugbon ti Agbejoro Oluwo Adatan naa, Babatunde Fabunmi yari pe dandan ni ki igbejo naa te siwaju labe ofin.

AWIKONKO gbo pe Mufutau fesun kan Oba Agura pe ona ti won gba ro oun loye ko tona rara, ati pe won ko ni eri gidi lati fi gbe e lese.

O ni se ni Nurudeen Olaleye to ni kii somo ilu Ira, nibi toun ti joye, tawon Baba e kan kole siluu naa ledi apo po mo awon kan, ti won ro oun loye. O ni lojo keji osu keji odun 2014 lawon Ogboni Gbagura ati Ogboni Ojo foun joye naa, toun si gba iwe eri e.

Sadeede lo ni Nurudeen Olaleye bere si ni da ilu Ira ru leyin tawon fi je Balogun Ira, o ni bo tile je pe kii somo ibe rara, Baba e kan kole sibe ni. O ni leyin toun ri iwe pe won da oun duro, igbese akoko toun gbe ni lati ri Oba Agura tawon wa labe e, toba naa si so pe oun ko mo nnkankan nipa e.

O ni siyalenu loun gbo pe won yan elomin in, eyi ti ko dun mo gbogbo awon toun je Oluwo le lori, idi niyii toun fi ro ile ejo lati gba oye oun pada, nitori o ni se ni won fee fowo ola gba oun loju.

Bo tile je pe awon tokurin naa fesun kan ko wa sile ejo, agbejoro lo kan yoju to si n bebe pe ki won fagile ejo naa.

Amo sa, awon omo Ilu Ira, ti Mufutau je Oluwo won ti fehonu won han lori iwa ti won ni Oba Agura naa hu, ti won si ni a fi ko  da pada sipo e.


AWIKONKO ba Oloye Nurudeen Olaleye soro lori esun ti won fi kan oun ati Oba Agura, Okunrin naa so pe oun ko le so nnkankan nitori oro naa ti wa nile ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI