Wahala de; Awon oloye Egba gbe Alake lo sile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 21, 2017

Wahala de; Awon oloye Egba gbe Alake lo sile ejo

Oro naa ti n koja oju tawon eeyan fi n bayii nitori wipe awon oloye naa ti wa so pe awon ko ni gba ki won maa fi obe eyin je won nisu, a fi kawon ja fun eto awon.

Oba Adedotun Aremu Gbadebo to je Alake tile Egba, Okukenu kerin lo ti foju bale ejo giga kan to wa ni Isabo, Abeokuta lojo Aje Monde to koja yii.

Bo tile je pe kayeefi lo si se opo awon to gbo nipa e pe ki lo le fa ti ori ade ile Egba yoo se lo kawo poyin rojo niwaju adajo ile ejo, sugbon oro naa ti wa foju han gbangba pe nitori oro oye jije lo faa tawon oloye kanka merin laafin Ake fi gbe Oba Gbadebo lo sile ejo.

Awon oloye naa ni; Oloye Abayomi Rotimi to je Oluwo Kemta, Oloye Ayinla Bankole to je Odofin Kemta, Oloye Zaccheaus Alatise to je Sakotun Kemta ati Oloye Rilwan Oresanya to je Are Ombo Kemta.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO leti se so, ninu ejo tawon eeyan naa pe ni won ti so pe Oba Alake, Adedotun Aremu Gbadebo yan Ogbeni Oluyinka Kufile gege bi Aro tilu Egba, ti ko si je kenikeni mo nipa bi won se yan okunrin naa.

Won so pe Ogbeni Kufile ko ye leni ti won le so pe o leto si oye nile Kemta, atipe eni tawon omo ilu Kemta ba fowo si gege bi oloye ni yoo je, kii se pe Alake lo maa fa eeyan kale gege bi ife okan e.

Awon eeyan naa war o adajo ile ejo lati da Alake, Gomina ipinle Ogun ati Adajo agba lowo ko lati ma se yan okunrin naa, iyen Oluyinka Kufile gege bi Aro tilu Kemta digba ti won yoo fi yanju oro naa.

Agbejoro won, Ogbeni Abass M.A tun so fun adajo naa pe, ona ti won gba yan Ogbeni Kufile gege bi Aro-Egba tako ofin to gbe oro oye jije odun 1957 kale. O wa ni ki ile ejo da okunrin naa duro, ki o si yee farahan tabi ki o maa se ojuse gege bi Aro-Egba.

Adajo naa, Onidajo Mobolaji Ojo wa sun igbejo naa si ojo kejilelogun osu keta odun yii. O so pe ki iwadi tubo tesiwaju lekunrere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI