Awon merin to fipa bomodunmokanla sun n'Ibadan ti foju ba ile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2017

Awon merin to fipa bomodunmokanla sun n'Ibadan ti foju ba ile ejo

Afi ki Olorun gba awon okunrin oloju kokoro lowo agbere nitori bi kini abe won se n fojoojumo ko ba won, to si n ran won lo sogba ewon.

Owo olopaa ipinle Oyo ti te awon afurasi odomokunrin merin kan ti won ko daruko won fipa ba omodebinrin eni odun mokanla sun nilu Ibadan.

Gege bi AWIKONKO se gbo agbegbe NNPC loro naa ti waye, ose abufo (detergent) ni won lomo naa n ba iya kiri lati le maa fi ri owo jeun latigba toun ati oko e ti ko ara won sile.

Ose naa ni won lomo naa kiri lojo tawon odo radarada agunmaniye yi pe e pe awon fee ra ose. Ose aadota naira ni won ni won ra lowo ti won si fun un ni eedegbeta naira pe ko fun awon ni seenji, sugbon omo naa loun ko ni seenji, ki won ba oun gbe oja oun.

Okan ninu won lo so pe ko tele awon lati wa lo gba owo e, sugbon nigba tomo naa rii pe won le gbe oun lo tabi ki won se oun nijamba, lo ba so fun won pe oun ko le tele won.

Gbogbo bi won se ni won n ro o pe ko tele awon, lomo naa n yari pe oun ko lo. Nigba ti won rii pe omo naa fee lagidi lo mu ki won woo lo sinu ile akoku kan to wa nitosi ibi ti won wa, nibi ti won lawon meji kan naa ti n duro de won.

AWIKONKO gbo pe Lesekese ni won ti bo pata e, ti won si ko ibasun fun karakara. Gbogbo bi won se lomk naa n sunkun, erin ni won n rin.
Igba ti won setan ni won ti omo naa sita pe ko maa lo, ti won si kilo fun un pe ko gbodo so fun enikeni, nitori bawon ba gbo pe o so, awon yoo luu.

Ekun ni won lomo naa sun de odo iya e, to si so nnkan to sele. "Moku mogbe modaran" lariwo tobinrin naa n pa ko too di pe awon eeyan yoju si, to si so nnkan tomo e so fun un, fun won.

Nibe ni won ti lo lati lo koju ija sawon onise ibi naa, ti won si ko gbogbo won lo sago olopaa.

Alukoro olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu komisana olopaa, Samuel Adegbuyi ti pase pe ki iwadii tesiwaju lori awon eeyan naa nitori pe iya omo naa lo wa so fawon olopaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI