Odaran paraku ni Prosper Kerry yi o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2017

Odaran paraku ni Prosper Kerry yi o


Laipe yii lowo olopaa ipinle Ogun te odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Prosper Kerry ti inagi je n je PMAN lori esun adigunjale.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won so pe Kerry atawon ore e meji ni won gbe okada lo si oteeli Tulamania ladugbo Odo-Nla Ogijo nipinle Ogun ti won si loo ja awon to wa nibe lole.

Won ni se ni Kerry atawon ore e sebi eni pe awon wa gba yara ni oteeli naa, kop e ti won de be ni won so pe won yo ibon sita ti won si ni kawon to wa nibe kawo soke.

Kerry ati okan lara won ni won ni won n wo awon yara kookan ninu oteeli naa lati gba owo atawon eru awon to wa nibe.

Ohun taa gbo ni pe, lara awon to wa ni oteeli lojo naa ni won ranse sawon olopaa Ogijo lati wa daabo emi ati dukia won. Loju ese ni won ni DPO Ogijo, Ogbeni Muhammed Tijani ti gbera pelu awon olopaa lati lo koju won.

AWIKONKO gbo pe bi Kerry atawon ore e ti rii pe awon olopaa ti de ni won ti doju ibon ko won, toro naa si di bolo o yago, ko too di pe owo palaba Kerry segi tawon meji toku sin a papa bora.

Abimbola Oyeyemi, to je agbenuso olopaa nipinle Ogun nigba to n soro naa fawon akoroyin so pe bo tile je pe owo tit e Prosper Kerry, sibe iwadii si n lo lori bi owo se maa te awon meji toku ti won na papa bora.

Agbenuso naa so pe, ibon kan soso lawon olopaa ri gba lowo e, sugbon Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe kawon olopaa FSARS gba ise naa se, ki won tesiwaju ninu ise iwadii lati rii pe owo te awon meji toku, ki won le gbe won lo sile ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI