Igbakeji Gomina ipinle Ogun ti yowo lori ejo to pe ni kootu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 11, 2017

Igbakeji Gomina ipinle Ogun ti yowo lori ejo to pe ni kootu

Lose to koja ni igbakeji gomina ipinle Ogun, Arabinrin Yetunde Onanuga so pe oun ti yo owo kuro ninu ejo toun pe nile ejo lori ti odomokunrin kan, Idris Yussuf to so pe o n ya aworan oun.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ojo kerindinlogun osu to koja ni igbakeji gomina naa fesun kan Idris pe o n ya aworan oun atawon moto to n tele oun laaro kutu ojo kan, nigba toun n lo sibi ise.

Lesekese ni Arabinrin Yetunde Onanuga ti gbe Idris lo si kootu pe ki ejo bere. Idris to je okan lara awon osise alaabo to n so ile kan to dojuko ile ti igbakeji gomina naa n gbe ninu Ibara lo bebe lojo naa fun idariji, sugbon ti Onidajo Olajide Ilo si fi oju aanu wo lojo naa pe ki won gba beeli ni egberun lona ogorun lojo naa, to si sun igbejo miran si ojo keje osu yii.

Sugbon nigba ti igbejo na yoo waye, Arabinrin Onanuga fi iwe ranse si adajo naa pe ko da ejo naa nu nitori pe oun ti dariji Idris, ko je ko maa lo layo ati alaafia.

Ninu leta ti won ni Arabinrin Onanuga ko si adajo lo ti so pe, oun dariji Idris latari gbogbo iwe ebe tawon eeyan Idris fi ranse soun, atipe won tun wa ba oun lati bebe fun Idris.

Nibe ni Olajide Ilo to je adajo ti so pe, oun ni nnkan toun tun fee so mo nigba ti eni to gbe ejo wa, to tun je igbakeji gomina ipinle Ogun ti so pe oun ko se ejo mo, fun idi eyi, ki Idris Yussuf maa lo layo ati alaafia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI