Ijoba ipinle Ogun ti bu owo lu Fijilante VSO gege bi ojulowo nipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 11, 2017

Ijoba ipinle Ogun ti bu owo lu Fijilante VSO gege bi ojulowo nipinle Ogun

Idunnu subu lu ayo lose to koja lago awon ajo eso alaabo ojulalakanfinsori, iyen Fijilante eyi ti Ogbeni Olusoji Ganzallo je oga agba fun nigba ti ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun so pe awon nikan lawon fun ni onte lori oro aabo nipinle Ogun.

Soji Ganzallo
Lori ariyanjiyan to ti n waye laarin ajo Fijilante mejeeji, iyen Vigilante Service of Ogun state, VSO ati Vigilante Group of Nigeria, VGN, ijoba ipinle Ogun so pe VSO nikan lawon le fowo gbaya le lori wipe won kun oju osuwon lati mu ki alaafia de ba ipinle naa nipa oro aabo to peye.

Amosun ninu oro e so pe pelu iranlowo ajo VSO nipinle Ogun, iwa odaran ti dinku lawon agbegbe ati igberiko, paapaa alaafia ti de saarin ilu, eyi to fi okan awon araalu lokan bale pe akoko ti to lati sun asundokan ki won si honrun.

Oga agba fun ajo VSO, Ogbeni Soji Ganzallo nigba to n soro dupe lowo Gomina Amosun fi aduro ti e, ati ipa to n ko nipa pipese awon ohun elo fawon eso alaabo kaakiri ipinle Ogun, eyi to mu ki ise rorun ti won n se rorun fun won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI