Ko si ooto ninu esun ti won fi kan awon oga agba FUNAAB o – Agbejoro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2017

Ko si ooto ninu esun ti won fi kan awon oga agba FUNAAB o – Agbejoro

Lori esun owo to le irinwo milionu naira ti won fi kan awon oga agba meta nileeko giga Ogbin nilu Abeokuta, iyen Federal University of Agriculture, Abeokuta, Ojogbon Olusola Oyewole, Senato Adeseye Ogunlewe ati Ogbeni Moses Ilesanmi ti won ni won ko je.

Won ni ko si otito ninu esun naa nitori pe ayederu iwe ni ajo EFCC n gbe kaakiri lati fi tako awon eeyan naa.

Bo tile je pe, Adajo Olatokunbo Majekodunmi ti sun igbejo miran si ojo kesan osu yii, iyen ojobo Tosde to m bo yii lati fi tesiwaju ninu ejo naa, eyi to bere lojo karundinlogbon osu kokanla odun to koja.

Ogbeni Wale Adesokan to je agbejoro Ogunlewe so pe ko si ooto ninu esun ti won fi kan okunrin naa nitori pe awon onte to wa lori awon iwe esun ti won fi kan an, kii se onte to je ojulowo.

O so pe esun kinni titi de ikejo, esun kejila si ikokanla lo je pe auruju ni won fi see, nitori pe won ko so pato iye owo to kan okunrin Ogunlewe, nitori naa, ki ile ejo da ejo naa nu.

Nigba toun naa n tako Ogbeni Adesokan, Ogbeni Benedict Ubi to je agbejoro fun ajo EFCC so pe oun tako oro naa, ki adajo sun igbejo naa siwaju lati fi sewadi ni kikun, lati le mo boya awon yoo yo oruko Ogunlewe kuro ninu awon ti won fesun kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI