Obasanjo lo ko mi si wahala o – Kashamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2017

Obasanjo lo ko mi si wahala o – Kashamu

Gbajumo senato nni, Senato Buruji Kashamu to n soju Ijebu East ti so pe Aare teleri lorileede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo lo ko oun sinu wahala toun n koju pelu ijoba orileede Amerika, iyen United State.

Kashamu
Kashamu soro yi lati fi tako esun ti ile ejo kan nile Amerika fi kan pe o lowo si gbigbe oogun oloro kokeeni ni nnkan odun merinla seyin.

Senato naa loun ko mo nnkan toun se fun Oloye Olusegun Obasanji to fi so pe odaran loun nipa gbigbe oogun oloro, eyi to fi je kawon Biritiko maa wa oun kaakiri lati lo jejo nibe.

O so pe aburo oun kan, Adewale Kashamu lo lowo si esun ti won fi kan oun ni odun merinla seyin, eyi to si mu ko lo jejo ni kootu meji otooto nile Amerika, eyi to si mu ki won da ejo iku fun un.

Senato Kashamu so pe bi enikeni ba gbiyanju lati so pe won fee gbe oun lo koju ijoba ile Amerika lati lo jejo lori esun toun ko mo nipa e, o lawon to po lo maa ku si nitori pe oun ti setan lati dide ogun.

“Eeyan meta, merin si marun lo maa ku”. Okunrin naa tun so pe ajo ajajangbara ti Oodua, iyen Oodua Peoples Congress loun yoo lo lati fi koju iru eeyan bee, koun le fi daabo bo emi oun.

O loun toun ko feran wahala loun maa wa lo gbe oogun oloro kokeeni lati fi da wahala si ara oun lorun, o ni ko see se nitori pe oun ko le se nnkan ti yoo tabuku ba oruko oun.

Nigba to n soro nipa ofin, Kashamu so pe ko bofin mu ki ijoba ile Amerika so pe awon fee wa gbe oun lati orileede oun lo sorileede won lati lo jejo nibe.

O loun jeri ijoba Buhari pe ko ni faaye gba ijoba ile Amerika lati wa gbe oun kuro lorileede yi nitori pe ijoba to bowo fun ofin ni ijoba to wa lori aleefa lowo.

Ninu oro e, o ni “Mi o lo sodo lo we, sugbon ni bayii, maa lo gba awon OPC to to ogoji. Maa maa ko won sinu oko mi kaakiri nitori ojokijo ti won ba pade mi, enikan gbodo pa enikan. Nitori pe mi o setan lati lo sibi kankan.

“Sugbon sibe, mi o ro pe ijoba yi le gba iwa ti ko bojumu bayi laaye pe ko sele. Mo gbagbo pe ijoba yi n bowo fun ofin pupo, nitori pe bi won ba fee se, won a ti see tipe.

“Obasanjo lo n ti won pe ki won wa mu mi pelu bo se n lo Sandra asoju ile Amerika sorileede yi tele, atawon miran pe ki won wa mu mi. bee lo tun n lo ri awon adajo, ki ni mo se?”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI