Owo te Adebayo atawon ore e ti won n jale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2017

Owo te Adebayo atawon ore e ti won n jale

Bi ijoba ipinle Ogun pelu ajosepo awon olopaa se n fonrere to pe awon ko fe iwa jagidijagan, ajinigbe, ajagungbale ati oniruuru iwa odaran mo nipinle Ogun, sibe se lo dabi eni pe awon eeyan ko ka oro naa kun, ti won si n fojoojumo daran.
 
Lojo Aiku Sannde ose to koja lowo olopaa ipinle Ogun te awon afurasi odaran merin lori esun idigunjale lagbegbe Oke-Ira, Agbara nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle Ogun.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni se lawon eeyan naa lo ja okunrin kan, Akeem Lateef lole egberun lona oodurun (#300,000) naira nileese e to ti n yo bulooku lagbegbe naa ni nnkan bi aago kan aabo osan ojo naa.

Awon merin naa ni Muse Ibrahim, eni odun metalelogun; Alashe Olaleye, eni odun  metalelogun; Efe Ejoh, eni odun merindinlogbon ati Olamilekan Adebayo.

AWIKONKO gbo pe, bawon eeyan se de adugbo naa ni won ti bere sii yinbon soke lati fi sise ibi won, ti won si bere sii fi ada, aake atawon eroja oloro min in ti won ko dani hale mo awon araadugbo naa.

Bi won se de odo Akeem Lateef to nileese bulooku naa ni won beere pe owo owo e da, tokunrin naa si so pe ko si owo kankan lowo oun. Okan ninu won lo da igbaju fun un pe ko gbe owo owo e fawon, ko too di pe o gbee le.

Ohun taa gbo ni pe, Akeem sese lo gba owo naa lati fi san gbese awon to je lowo, ko si fi eyi toku sise sori igba fawon onibara e, ko too di pe awon adigunjale naa de lati wag baa lowo e.

Lara awon araadugbo toro naa soju e ni won ni won te awon olopaa laago pe awon adigunjale tun ti n sise won, ki won tete wa koju won. Loju ese ni won lawon olopaa ti gbera lati lo kapa won.

AWIKONKO gbo pe, bawon odaran naa se gbo pe awon olopaa ti de ni won ti koju ibon si won lati bawon jijakadi. Sugbon nigba ti won rii pe owo won ko ka awon olopaa lo mu ki won fee na papa bora.

Nibe ni won ti mu awon merin towo te naa bale, tawon toku si juba ehoro.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi gege bo se so, o so pe nigba ti won foro naa to DPO Agbara, Ogbeni Yemi Oyeniyi leti lo ti ko awon olopaa leyin lati lo doju ija ko won.

Abimbo so pe nibi ijakadi naa lowo ti te awon merin naa, tawon yooku won si na papa bora pelu owo ti won gba lowo okunrin naa, sugbon awon nigbagbo pe laipe laijina, owo olopaa yoo te won.

O so pe awon nnkan oloro ti won ri gba lowo won ni aake, apo saka ti won ko obe si, fila iboju meta ati igbo.

Agbenuso naa wa fi kun oro e pe, Ahmed Iliyasu ti pase fawon olopaa FSARS pe ki won tesiwaju ninu iwadii lati rii pe won rowo to awon toku ti won salo, lati le fi iya ofin je won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI