Adajo ti ni kawon olopaa si fi Seun Egbegbe pamo si tesan won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2017

Adajo ti ni kawon olopaa si fi Seun Egbegbe pamo si tesan won


Won ni odaran paraku ni

Seun Egbegbe ati Ayomide Oyekan
Oro naa ti koja oju tawon eeyan fi n woo bayii, nitori pe afaimo ki okan lara awon gbajumo to n sagbateru ere ori itage, tiata nni, Olajide Kazeem topo mo si Seun Egbegbe ma sewon lori esun ole jija ati gbajue to n se kaakiri, eyi ti won fi kan an.

Bi e o ba gbagbe, ojo mefa pere lo ku ki Seun Egbegbe foju bale ejo lori esun ti won fi kan lojo kejilelogun osu kokanla odun to koja wipe o n gbiyanju lati ji foonu olowo nla mesan towo won to milionu merin naira salo lagbegbe Computer Village, ikeja nilu Ekoo.

AWIKONKO gbo pe oro naa lo gbe dele ejo, bo tile je pe milionu kan naira ni adajo to wa nidi ejo lojo naa so pe ki won fi gba beeli e pelu oniduro meji ti won n san owo ori won deedee. Adajo naa, Arabinrin Y.O. AjeAfunwa sun igbejo miran si ojo kejo osu yii, iyen osu keji odun 2017.

Iyalenu lo tun je nigba ti won tun mu okunrin naa nibi to ti lo lo gbajue fawon awusa meji ti won n paaro owo dola si naira. Won loo so fun won pe oga awon dokita loun ni osibitu kan to wa nitosi ibi ti won wa.

Gege bi AWIKONKO tun se gbo, lati odun 2015 ni won so pe Seun Egbegbe ti n sise buruku naa, to n lu awon eeyan ni jibiti owo, atawon ohun ini won, bo se n lu won ni jibiti l’Ekoo, bee lo n lu won ni gbajue n’Ibadan, bakanna ni ko tun je ki won gbadun l’Ogun, gege bi AWIKONKO se gbo.

Seun nigba to ji foonu
Nigba ti owo palaba e segi lodun to koja, opo awon tokunrin naa ti lu ni jibiti ni won yoju, ti won si wa n tako o ni tesan awon olopaa Area F l’Ekoo, sugbon oun taa gbo ni pe, awon kan ni baa bebe, ti won si pa ina oro naa, nitori won ko fee koro naa ju bee lo.

Lojo ti asiri e tun tu l’Ojobo Tosde ose to koja pelu enikeji, Ayomide Oyekan, tawon olopaa si gbee lo si tesan won, nibe lawon eeyan tun ti bere sii yoju lati tu awon asiri ikoko e lorisirisi nipa iwa odaran to hu seyin. Nibe ni won ti mo pe osu kejo odun 2015 ni won ti n wa a.

AWIKONKO gbo pe esun merindinlogoji ni won fi kan Seun Egbegbe ati Ayomide Oyekan, igbakeji e nile ejo, eyi ti won loo lodi si ofin orile ede Naijiria. Yato sawon ti won loo ti lu ni jibiti lorisiri ona, ko din ni ogbon lawon ti won se pasipaaro owo to tun lu ni jibiti lati osu kejo odun 2015 si osu keji odun yii, iyen 2017.


 Lara awon to ti lu ni jibiti ni Mohammed Sanni, milionu meji ataabo naira (N2.46m) lojo kinni osu kinni odun yi; Jubriala Ado, milionu kan ati oodunrun naira din legberun meta (N1.257m) lojo kesan osu kesan odun 2016; Hassan Amodu, egberun lona eedegberin naira (N600,000) ninu osu kinni odun 2016; Sanni Hassan, milionu kan ataabo naira (1.43m) pelu milionu meta din die owo Euro (2,750Euro) ninu osu kejo odun 2015; Saidi Abdullahi ni 700,000 lojo kejidinlogun osu kerin odun 2016.

Bakanna ni Atairu Abdullaahi, milionu kan naira lojo ketalelogun osu karun odun 2016; Abdullahi Babadisa, N650,000 ninu osu kinni odun 2016; Abdurawan Hassan, milionu kan ataabo lojo kinni osu kinni odun 2017; Suraju Garuba, N850,000 ninu osu kefa odun 2016; Abdullahi Mumini, milionu meji naira (N2.15m) losu kesan odun 2016; Garuba Hassan, N700,000 lojo kewa osu kinni odun 2016; Sanni Muhammed, milionu meji naira (N1.89m); Barawo Abdullahi, milionu meji ataabo naira (N2.6m); Yahu Alidu, milionu meji naira (N1.75m); Tairu Musa, milionu meji naira (N2m).

Egbegbe ni ti asiri e tu
Bee naa ni Muhammed Bello, oodunrun dola ($300); Muhammed Usman, egberun lona eedegbeta naira (N450,500); Suleiman Shehu, N1.276m; Nairu Musa milionu kan naira (N1.007m); Sanni Muhammed milionu kan ataabo naira (N1.6m) ati egberun meta dola ($3,000).

Awon miran tun ni Umaru Haruna, milionu meji naira din ni egberun lona oodunrun naira (N1.7m); Abubakar Musa, egberun merin dola ($4,000); Abdulrasaq Sanni, N1.7m; Abdullahi Babatunde, milionu meta naira (N2,77m) ati bee bee lo.

Agbejoro olopaa, Ogbeni Effiong Asuquo nigba to n soro niwaju Onidajo A.O Gbadamosi so pee sun ti won fi kan won lodi si ofin kejo labala iwe odaran odun 2006, to si ni ijiya labe ofin.

Bo tile je pe gbogbo esun merindinlogbon ti won ka si Seun Egbegbe ati Ayomide  leti ni won so pe awon ko jebi e pelu alaye. sugbonOgbeni Innocent Anyigor so pe ki adajo naa ma se fi oju aanu wo awon mejeeji lati le je ki won gba beeli won, nitori pe o seese ki won tun lo lu jibiti nibo miran ti won ba fi won sile.

Innocent ro ileejo naa pe ki won pase pe kawon odaran mejeeji naa si wa lakata awon ki o si mu ojo ti igbejo miran yoo waye.

Naigba toun naa n soro, Onidajo Gbadamosi so fun Agbejoro Oguntoyinbo wipe oun n gbero lati pase pe ki won gba beeli won tele ni, sugbon, ko seese mo nitori pe o seese ki won tun lo daran nibo miran.

O wa sun ojo igbejo miran si ojo kerinlelogun osu keta odun yii, iyen 2017.

Nile ejo lojo naa, opo lo n soro labele pe ki won ju okunrin naa sewon lesekese nitori pe o ti pa opo awon eeyan lekun. Bee ni AWIKONKO tun gbo lati enu awon araalu to soro nipa Seun Egbegbe wipe oogun isiju ni Seun n se, lati le maa fi lu jibiti. Won so pe ibi to ti n ri owo ti e niyen.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI