Orin ti bere sii dowe bayii nipinle
Ogun lori bawon kan se n so pe ki Senato to n soju ekun kan nipinle Ekoo, to
tun je alaga leka eto ikansiraeni nile igbimo asofin agba nilu Abuja, iyen
Senato Solomon Olamilekan Adeola topo mo si YAYI, eni
topo awon omo ipinle Ogun ti n nigbagbo ninu e pe oun ni won yoo dibo fun gege
bi gomina lodun 2019 gege bi omo Yewa lo toka si orirun e nile naa.
Senato Yayi |
Bo tile je pe gbajumo oloselu naa ko
tii lo odun kan tan gege bi Senato to n soju ipinle Ekoo, tawon omo ipinle Ogun
ti n gbe onte fun un pe ko maa bo lati wa dupo gomina lodun 2019.
Ka ma figba kan bo okan ninu, Kabiyesi
Oba Alaye tile Yewa, Oba Gbadewole Kehinde Olugbenle naa ko gbeyin ninu awon to
n so pe oun ni kawon eeyan tele, paapaa awon Yewa lati le ri opa ase tawon ti n
le latodun 1976 gba, bo tile je pe ko tii so sita gbangba.
Gege bi AWIKONKO se gbo, Senato
Olamilekan Adeola ti lo odun mejo nile igbimo asofin nipinle Eko, to si gbabe
depo Senato to n soju Ekoo.
Yoruba bo, won ni adie kii je ifun ara
won, lara awon omo ile Yewa naa lo n so pe ki sobia too degbo, ki Senato naa
tete toka si orirun e nile Yewa nitori pe awon ko mo o rara gege bi omo Pahayi-Ilaro
tawon eeyan n pe kaakiri lori ero ayelujara atawon ipade bonkele ti won n se.
Won so pe ko si idile to n je Adeola ni
Pahayi-Ilaro nitori pe gbogbo idile lawon mo nibe, atipe ki lo de ti ko fi ronu
lati wa dupo gomina nipinle Ogun lodun 2014, to fi je pe leyin osu merin to di
Senato nipinle Ekoo, lo to sese ronu pe omo ipinle Ogun loun.
AWIKONKO gbo pe, gbara ti Senato YAYI
de sipinle Ogun gege bi omo Yewa to mu ko sare lo ko ile si Ilaro lati so pe
omo Pahayi-Ilaro ti Ishaga Orile, nijoba ibile Abeokuta North loun.
Bo tile je pe iroyin kan ti a gbo ti a
ko tii fidi e mule titi di asiko yi so pe, se ni Oba Jogan le Senato YAYI kuro
nigba to so pe oun ko le fowo soya nipa orirun e gege bi omo Joga ni Yewa
nijoba ibile Yewa North loun je, eyi to si muu lati lo ko ile e naa silu Ilaro
to si so pe omo Pahayi-Ilaro loun je.
Nigba ti won n toka sawon to ti sise
nipinle Eko ko too di pe won pada sipinle won lati lo di gomina, ni won ti toka
si Oloye Olusegun Osoba, Otunba Gbenga Daniel, Senato Ibikunle Amosun bakanna
ni Gomina tele nipinle Osun, iyen Ogbeni Rauf Aregbesola.
Bee naa ni won toka sawon tipo gomina
ipinle Ogun wu, bii Gboyega Isiaka, Abiodun Akinlade, Kolawole Lawal atawon mi
in.
Oro buruku toun terin, nigba ti won so
pe ko loo mu awon obi e wa, to ba si je pe won ti ku, ko toka si ibi ti won sin
won si nitori pe awon ko tii le toka si idile to n je Adeola ni Pahayi nilu
Ilaro.
Bakanna ni won ni ko toka sawon molebi
e to si wa laye to je Pahayi ni won n gbe titi di asiko yii. Won ni ki Senato
naa mu awon iwe atawon foto aridaju to le fi awon lokan bale pe looto ni pe omo
Yewa loun ko ma lo je pe won fe lo gbaju e fawon ni.
AWIKONKO gbo pe gbogbo akitiyan ti
Senato YAYI gbe lati so pe omo bibi Ishaga ati Joga loun lo ja si pabo nigba
naa, eyi gan an lo faa ti won fi n beere so pe ki ba dara tokunrin naa ba le
jokoo e jeje sipinle Ekoo, ko si maa gbadun aye e lo nibe.
Lara awon to dipo oselu mu nigba
ti won n toka si orirun won ni won ti toka si Senator Dada gege bi eni to wa
lati idile oba ni Ota; Tunji Akinlade gege bi ‘omo Baba onipako’ ni Owode;
Gboyega Isiaka gege bi ‘Omo Iya Adinni’ ni Imeko; Kolawole Lawal gege bi ‘Adele-Oba’
ti Oke-Odan, bee naa ni olori ile igbimo asofin ipinle Ogun, Suraju
Ishola Adekumbi gege bi ‘Omo Baba Elepo’ ni Ayetoro.
Oloye Akande Omoniyi to je Jagunmolu
Joga-Orile ati Mayegun Igan-okoto ni Yewa nigba to n soro lose to koja so pe o
ti to odun metalelogun toun ati Senato Yayi ti jo n ba ore won bo, toun si mo
awon obi e ko too di pe won ku.
O so pe gbogbo igba toun ba lo wo won
nile ni Alimosho leyin tawon pari eko ICAN jo loo se ni iya to bi Yayi maa n pe
oun ni “Jamiu Baba Oko mi”, to si maa n so pe omo Yewa lawon. sugbon awon eeyan
so pe iro lokunrin naa n pa.
Won ni omo tani YAYI, nitori pe awon ko
setan lati pe e ni ‘omo atowunrinwa’, nitori na ni won se n tete so fun un pe
ko toka si orirun nile Yewa.
No comments:
Post a Comment