Asiri Francis atawon ore e tu l'Ayetoro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2017

Asiri Francis atawon ore e tu l'Ayetoro

Aso immigration ni won fi n lu jibiti

Boroboro ni Francis Akete atawon ore e meji, Muheedeen Dikou ati Inyas Akete n ka logba awon osise to n ri soro wole wode lorileede Naijiria, iyen Nigeria Immigration Service nigba towo palaba won segi lose to koja.

Gege bi AWIKONKO se gbo, agbegbe Ayetoro nijoba ibile Yewa North ni won ni asiri won tu, ti won si ri ibon, oogun, ayederu kaadi idanimo ti ajo naa ati okada meji gba lowo won, eyi ti won ni won fi n lu awon eeyan ni jibiti owo ati eru.

Lale ojo Eti Fraide to lo lohun ni won ni awon osise ajo naa mu won lakoko ti won n kaakiri lati mo nnkan to n lo. Nigba ti won de ibi ti won wa ni won beere lowo won pe ekun ibo ni won wa, sugbon ti won ko le dahun daadaa.

Nibe lara ti fu won pe ayederu lawon eeyan naa, atipe ise buruku ni won n se nibi ti won wa, ti won si so pe awon gan an ni won ba ajo naa loruko je.

Okan lara won, Muheedeen nigba to n soro so pe bo tile je pe ibon naa ko ni iwe ase, sugbo baba oun lo fi n sise Fijilante. O so pe oun n fi oogun ti won gba lowo oun daabo bo ara oun ni.

Oga agba fun ajo naa nipinle Ogun, Ogbeni Ajibola Bayeroju awon eeyan naa ni won n da alaafia awon araalu laamu, ti won si n ba oruko awon aje, sugbon asiri won tu lakoko tawon eeyan won n sise leyin ti won ri ase gba lati Olu ile ise won nipinle Ogun pe ki won lo le awon ti kii se omo orileede Naijiria ti won ko ni iwe ase kuro.

Ajibola so pe awon yoo fa awon eeyan naa le awon olopaa lowo leyin tawon ba pari ise iwadi won, ki won baa le tesiwaju idajo to ye lori won.


O wa ro awon to n gbe orileede yii lai ni iwe ase ki won tete kuro nitori pe awon ko ni fi aaye gba won lati duro lorileede yii. O ni eni ti won ba mu yoo foju wina ofin ijoba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI