Won ni Olu Asasin ni Oba Nofiu Adeyemi, kii se Onijaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2017

Won ni Olu Asasin ni Oba Nofiu Adeyemi, kii se Onijaye

Sugbon Oba naa ni iro ni

Awon oloye Gbagura labe Oba Adedayo Halid Olaloko, Sobekun keji to je Agura ti Gbagura ti so pe ki Oba Nofiu Adeyemi Otunba to n pe ara e ni Onijaye tilu Ijaye yee pe ara e be mo nitori pe kii se nnkan ti won fi je lo n pe ara e, bikose pe ona eru lo fee gba lati fi je Oba Onijaye.

Nigba ti won n soro pelu Ase ti Agura ti Gbagura Abeokuta fun won, iyen ninu Aafin Kabiyesi naa lojobo Tosde ose koja, won so pe Olu Asasin tilu Ijaye Titun ni won fi je ni nnkan bi odun meje seyin labe Gomina ana, Otunba Gbenga Daniel.

Won so pe iwe eri ti Oba Nofiu n gbe kaakiri gege bi Oba, Abule Asasin to wa lona Rounda, Abeokuta ni ipo naa mo, nitori pe abe Gbagura ni gbogbo Ijaye wa, atipe Oba Gbagura nikan lo ni ase lati yan Oba sibe.

Oloye Abiodun Adenekan to je Akowe igbimo awon oloye nilu Gbagura nigba to n soro so pe lowolowo bayii, ko tii si nnkan to n je Onijaye ti Ijaye ni Gbagura gege bi Oba Nofiu ti n pe ara e. O ni Olu Asasin tilu Ijaye Titun ni Ijoba ipinle Ogun fun gege bi iwe eri to n gbe kaakiri.

Adenekan so pe gege bi ilana ni Gbagura, ki eeyan to le je Oba, o gbodo koko je Baale, eyi lo faa ti won fi fun nipo Baale lodun naa lohun, ko too di pe won soo di Oba, iyen Olu Asasin.

Won ni iyalenu lo je fawon pe, gbara ti won fi je Olu Asasin lo sare lo ra moto, kaka ko gba nomba Olu Asasin si, Onijaye lo gba si, lesekese ti Oba Gbagura ti ri lo ti pe akiyesi e si i pe ko ma se koja aaye e.

O ni Kabiyesi pe e nigba naa, o si gba lamoran lorisirisi, sugbon pelu agidi okan e, lo n so pe ko seni to le pase foun.

Won ni aimoye leta lawon ti ko ranse si Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo, sugbon ti Alake so fun un pe kii se ipo ti won yan an fun lo n pe ara e, latigba naa ni won lo ti bere sii sa ni Aafin Ake.

Won so pe Oba Alake ti fesi si leta tawon ko nipa Oba Nofiu gege bo se n pe ara e ni Onijaye pe awon yoo wa nnkan se si laipe, esi Alake ni won n reti.

Bakanna ni won lawon ti ko leta sijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun ati Komisana to n ri soro oye jije nipinle Ogun, Babajide Ojuko, esi ni won n reti.

Lati mo boya won ti gbe oro naa de ile ejo, Oloye Adenekan so pe awon ko nilo lati gbe e lo sile ejo, O loun gan an ni yoo lo sile ejo lati lo o pe ejo kotemilorun to ba mo pe o da oun loju.

Oba Nofiu nigba toun naa n fesi soro naa lori foonu lati gbo tenu e, o so pe iro lawon Oloye naa n pa mo  oun, atipe nitori wipe won ti mo pe oun ko si nile lo je ki won ri aaye lati maa so isokuso kaakiri.

O so pe awon iwe eri to fese rinle pe Onijaye loun lo wa lowo oun, atipe lara awon Oloye ti won n soro naa wa nibe lojo ti won lo gba ade lowo Alake, bo tile je pe o so pe oun ko tii le soro pupo bayii nitori orileede Amerika toun wa, o ni nnkan toun lo se nibe. O ni toun ba de ni ipari osu yii loun yoo fi awon iwe eri naa han wa.

Asiri kan to tun tu si wa lowo ni pe, lara awon ti won pe ipade awon oniroyin naa fee je Oba Onijaye.

Lara awon ti won wa ni ijoko lojo naa ni Oloye Abiodun Adenekan to je Akowe igbimo oloye ni Gbagura; Oloye Adesola Obe to je Balogun Ijaye Kukudi; Oloye Aremu Adeniji to je Oluwo Ijaye; Oloye Kola Popoola to je Lukotun Kukudi.


Awon min in ni, Jaguna Ijaye Obirinti; Ekerin Ojoo Gbagura; Osi Ibadan Gbagura; Apena Idere Gbagura; Akogun Idere Gbagura; Bada Gbagura; Olori Oluwo Ekoo Gbagura ati Apena Ojoo Gbagura.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI