Joseph ati Adebayo to faso soja lu jibiti wo gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 14, 2017

Joseph ati Adebayo to faso soja lu jibiti wo gau

"E pa wa sile, e ma pa wa sita" loro to n jade lenu Joseph David ati Adebayo Olanrewaju ni tesan olopaa, Eleweran Abeokuta lojobo Tosde ose to koja leyin tasiri won tu.

Joseph ati Adebayo
Gege bi AWIKONKO se gbo, agbegbe Agbado lowo ti te won pelu aso soja ti won fi n lu awon araalu ni jibiti owo ati eru orisirisi.

Won lawon odaran naa ko fawon ara agbegbe naa lokan bale rara, nitori aso soja ti won fi n boju sise ibi won.

Nigba ti isu maa dile leyin asunsuje won losan Ojobo Tosde naa, won lawon lokunrin meji ti won na, ti won si se lese lo lo fejo sun awon olopaa pe awon soja kan ti sise se.

Ogbeni Paul Oniyo ti won lagbofinro ni ati Chima Solomon ni won loo so fawon olopaa Agbado pe awon eeyan naa fi iya he awon lona ti ko bofin mu.

Loju ese ni won ni DPO ekun naa, Ogbeni Abioye Shittu ko awon olopaa soko lati lo mo nnkan to n sele, sugbon won ni se lawon eeyan naa n gbon lohun nigba ti won ri awon olopaa, eyi lo mu ki DPO naa ko won lo si tesan lati lo foro wa won lenu wo.

Nigba ti won de tesan lasiri won tu sawon olopaa lowo pe ogberi ni won, won kii sawo awon soja. Lesekese ni Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ji won maa kp won bo ni Eleweran, nibi ti won ti n ka bi eye ayekooto.

Abimbola Oyeyemi nigba to n soro so pe iwadi si n lo lowo lori awon ise ibi ti won ti se seyin. O ni awon eru soja lpris

O so pe bo tile je pe Komisana won ti pase pe kawon SCIID tesiwaju ninu oro won, sugbon leyin iwadi, o see se ki won foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI