Owo te Musa atawon ore e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 14, 2017

Owo te Musa atawon ore e

Moto oga ile iwe giga Crawford ti won ja gba
Republic of Benin ni won ta si

Afi bi eni to je furo adie loro Musa atawon ore e meta towo palaba won segi lose to koja ri, nigba ti won se bere sii ka gbogbo oran ti won ti da seyin.

Musa atawon ore e
Gege bi atejade ti Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi fi sita lojo Aje Monde ose to koja, agbegbe kan ni Seme ti won farapamo si lasiri won ti tu nigba tawon olopaa FSARS lo koju ija si won.

AWIKONKO gbo pe lojo ketadinlogbon osu kinni odun yi ni Hassan Musa, eni odun marundinlogbon; Segun Idike, eni odun mokandinlogun; Adewale Rasak, eni odun metadinlogbon; ati Keneth Ohimai ti won loun lo dagba ju laarin won, ti won so pe eni odun mejidinlogoji ni lo dena gba moto Giwa ileeko giga Fasiti Crawford to wa ni Igbesa, ipinle Ogun, Ojogbon Rotimi Ajayi.

Jiipu Toyota Highlander won lawon odaran naa ja gba lowo Ajayi pelu ibon lowo loju ona Atan si Igbesa laaro kutu ojo naa, nigba ti won so pe, okunrin naa n lo si ibise e lojo naa ni.

Loju ese toro naa ti sele ni won lokunrin naa ti lo fi to awon olopaa leti, tawon yen si bere sii sise iwadi won.

Lojo ti isu maa dile leyin oloko won, fun bii wakati kan aabo gbako lawon odaran naa atawon olopaa fi koju ibon sira won, bi eni pe won sere tiata loro ri lojo naa, to si di bolo o yago laarin won.

AWIKONKO gbo pe okan lara won ti ibon ba legbe, iyen Joseph Housus ri aaye lati na papa bora pelu ota ibon lara e. Inu ilu kan ti won pe ni Ajase ni Republic of Benin nibi to ti n gba itoju ni won ti rii mu, sugbon gbogbo akitiyan lati mu wa si Naijiria lo ja si pabo.

Ninu oro ti Musa so lo ti jewo pe Republic of Benin lawon ta moto naa si, atipe kii se akoko tawon maa se iru nnkan bayii niyii.

Abimbola so pe, ibon merin ati ota ibon to to ogbon ni won ri gba lowo won, bo tile je pea won si n gbe igbese lati bawon agbofinro nibe soro lati gba moto naa pada fun eni to ni.

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti wa gbawon olopaa FSARS niyanju lati tubo tepa mo ise won, ki won le rii daju pe won pa iwa odaran run patapata nipinle Ogun.

Bakanna lo wa ro awon araalu lati tubo maa fawon olopaa ni iroyin nipa ibi ti won ba ti kofiri awon odaran, nitori alaafia won lo je olopaa logun julo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI