Leyin osu marun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 27, 2017

Leyin osu marun

Awon alaga idagbasoke si n lobi kiri nipinle Ogun

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi lawon alaga ijoba ibile ati idagbasoke, iyen LCDA metadinlogoji ti ijoba ipinle Ogun fi kun ijoba ibile ogun to wa nipinle naa si n wotun wosi lori bi won yoo se ni ofiisi ti won.

Gomina Amosun
Bi e o ba gbagbe, osu yi gan lo pe osu marun leyin ti idibo ijoba ibile ti waye nipinle Ogun, sugbon latigba naa lawon ti won ni won dibo yan naa si n rin kaakiri lati wa ibi ti won yoo maa lo gege bi ofiisi ti won.

Gege bi okan lara awon to wa nipo oselu taa fi oruko bo lasiri to gbe oro naa si AWIKONKO leti se so, o ni bo tile je pe ona eru ni won fi gbe awon alaga atawon kanselo naa wole, sibe won si n lobi kaakiri lati wa ile tabi yara ti won yoo maa lo gege bi ofiisi.

Ninu osu kewaa odun to koja ni idibo ijoba ibile ati idagbasoke waye nipinle Ogun, to si je pe egbe oselu All Progressive Congress, APC nikan lo yege laarin awon egbe oselu bii marun to kopa nibi eto idibo naa.

Sugbon ninu osu kokanla ni Komisana foro oye jije ati idagbasoke agbegbe nipinle Ogun, iyen Oloye Babajide Ojuko se ibura fawon eeyan naa to si seleri owo atawon eto to to si won fun won.

Leyin naa ni Gomina ipinle Ogun, Asofin Agba Ibikunle Amosun ba won se ipade toun naa si se ileri owo ile, aso ati dukia to je gege awon ohun ti won leto si fun won.

O seni laanu pe latigba ti Ojuko ti bura fun won, to si seleri lorisirisi, ti Gomina Amosun naa se ileri ti e titi di asiko yi, ko tii seni to le fowo soya pe oun ti ri eto tijoba ipinle Ogun seleri e fun won gba, bo tile je pe won ri owo osu gba diedie.

Lara awon alaga ijoba ibile ati idagbasoke agbegbe tuntun ti won sese yan yi ti bere sii fehonu han labele si gomina Amosun bo tile je pe ko seni to to be ninu won lati gbin nigba to je pe ohun to foju han kedere fawon araalu ni pe ona eru ni won fi yan won.

Gege bi iroyin to tun te AWIKONKO leti se fi han fun wa, ni pe opo awon akanse ise to to si awon alaga ijoba ibile ni won ko tii bere. Bee, lara awon yara kan ti won ya sile fun ijoba ibile Abeokuta North ninu ogba ile eko Owu African Church Central to wa ni agbegbe Ita-Iyalode nilu Abeokuta ni won si tipa ti ko si ni lilo fawon to to si.

Bakanna ni ijoba ibile idagbasoke Remo Central to wa ni Iperu lona Ilishan-Remo ni won ti pa, ti ko si ri eni lo ohun. Bee naa ni won ko tii pari ofiisi ijoba ibile idagbasoke to wa ninu ogba ijoba ibile Abeokuta South tele lagbegbe Ibara titi di bi a ti n koroyin yi.

Alaga ijoba ibile ati idagbasoke Abeokuta South/South nikan ni ofiisi e si pari ninu yara ikawe kan to wa ninu ogba ile-eko alakobere to wa ni Idi-Aba, Abeokuta.

Ohun ti a tun ri gbo ni pe ogba ijoba ibile ati idagbasoke to wa ni Ijebu Ode South lagbegbe Oke-Aje ati eyi to wa ni Ketu lagbegbe Tata, iyen ni ijoba ibile yewa atijo ni ko dun un wo loju lori bi won se so pe awon ibe yen ti baje, to si n fe abojuto.

Agbalo-agbabo, kaka ki alaga ijoba idagbasoke Abeokuta North, Ogbeni Taofeek Olabode bebe fun ofiisi e, nise lo so ile e to wa ni Lafenwa di ofiisi nibi to ti n dawon eeyan lohun. Bakanna loro ri pelu alaga idagbasoke Sango/Ijoko, iyen Ogbeni Fatai Lawal, toun naa so ile e di ofiisi.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI