Saheed Osupa sa fun Pasuma nibi ayeye ti Fancy Aye Alamu se - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 27, 2017

Saheed Osupa sa fun Pasuma nibi ayeye ti Fancy Aye Alamu se


Osupa ati Pasuma
Opo awon eeyan to wa nibi ayeye ifilole kaseeti tuntun ti gbajumno agba onifuji nni, Fancy Aye Alamu se ni gbongan ile ise telifisan LTV 8 to wa ni Agidingbi, Eko lose to koja ni ko mo idi ti Saheed Osupa fi sare jade nibi ayeye naa.

Lojo Aiku Sande ose to koja ni gbajumo Fancy Aye Alamu pe awon osere onifuji meji nni lati wa lara awon ti yoo sere nibi ayeye ifilole kaseeti to pe akole e ni “Na God”.

Bi ayeye naa se n lo lowo ni Saheed Osupa ti koko debe, ko si pe lo bo si ori itage, to korin. IROYIN OWURO gbo pe bi onifuji ohun se n korin lowo niroyin kan sii pe Wasiu Alabi Pasuma naa ti de, to si fee wo gbongan ibi ayeye naa.

Ariwo yi ni won ni Saheed Osupa gbo to fi korin naa paapaapaa, koda, gbogbo awon to fee ki ni ko duro ki won, to si fee ssare tete bo sita, sugbon bo se bo sita si enu-ona abajade lo se konge Pasuma.

IROYIN OWURO tun gbo pe, iyalenu lo je pe se ni Osupa koko gboju bi eni ti ko rii, to si fee gba egbe e koja, sugbon bi Pasuma se rii lo fi ejika e gba legbe, ko too dipe won di mo ara won.

Won o lo ju iseju kan ti Osupa fi kuro nibe lo sibi to tun ti fee sere ninu ogba redio naa sugbon awon to wa nibe ti won ri nnkan to sele ni won so pe se ni Osupa mo on-mo sa fun Pasuma, atipe won ni kani o mo pe Pasuma tete maa de sibi ayeye naa, boya ko ba di bi owo irole koun too yoju.

Lara awon osere to tun sere nibi ayeye naa ni Abass Akande Obesere, iyen Omorapala. Bakanna ni Sunny Ade, Kollington Ayinla ko gbeyin nibi ayeye naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI