Nitori obinrin, Adebisi yinbon pa Asimiyu n'Ijebu Igbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 1, 2017

Nitori obinrin, Adebisi yinbon pa Asimiyu n'Ijebu Igbo

Adebisi
A fi bii sinima agbelewo loro naa ri lojo Aiku Sannde ose to koja nibi ti okunrin kan, Adebisi Akinrinmade, eni odun metalelogoji ti yinbon pa Ademola Asimiyu, eni odun merindinlogoji nitori obinrin kan soso tawon mejeeji n ja si.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago meta ojo naa nisele naa waye, ni Abule Ajebo, Ijebu-Igbo, ipinle Ogun loro naa sele, nigba ti won so pe inu igbo kan labule naa lawon mejeeji ti koju ija sira won, ko too di pe enikan gbemi min in.

Ohun ti a ri gbo ni pe, Ademola Asimiyu ati Adebisi Akinrinmade ti jo n leri si ara won, ojo ti pe, ti won si so pe Asimiyu maa n so pe oun loun yoo gbemi Adebisi, toun yoo si ri obinrin naa fe gege bi aya.

Bo tile je pe ohun ti Adebisi n so lago olopaa ni wipe, Asimiyu ko too di pe o jade laye, lo ti maa n so pe oun gba iyawo mo oun lowo, oun ko si nii gba, a fi ti oun (Asimiyu) ba gba iyawo oun pada.

Adebisi so siwaju pe, “Asimiyu ti maa n so pe, lojo tawon ba maa fojuriju nibi ti ko ti ni si eni ti yoo la won, oku meji yoo ba Olorun lalejo lojo naa. O ti so pe, a fi toun ba pa oun.”

AWIKONKO gbo pe, lojo ti isele buruku naa maa n waye, inu oko ni won so pe Adebisi ati obinrin naa ti m bo, ko too di pe Asimiyu pade won lona, to sib ere sii so pe, asiko ti to toun yoo gba iyawo oun pada.

Wahala naa ni won fa titi ko too di pe won so pe Asimiyu fa ada yo lati fi sa Adebisi, sugbon iyalenu lo je nigba ti won so pe, ki Asimiyu too gbe ada e soke lati fi sa Adebisi, Adebisi ti fa ibon e yo, o si daa bo Asimiyu.

Loju ese ni won so pe Asimiyu subu lule, o si gbemi min in. Won so pe ko ranti pariwo “ooro ooo” bii ti fiimu agbelewo ko too di pe elemi gba a mo lowo.

Obinrin ti won n ja si
Alukoro olopaa ipinle Ogun, nigba to n so fawon akoroyin, o so pe awon toro naa soju e lo lo so fawon olopaa ekun Ijebu Igbo, ko too di pe DPO Agene James lwaju awon olopaa. O ni lesekese ni Komisana won, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won mu Adebisi wa si Eleweran lati foro wa lenu wo.

Abimbola so pe bo tile je pe, Komisana ti so pe ki won gbe okunrin naa lo si odo awon olopaa SCIID, o ni won ti gbe oku Asimiyu lo si motuari fun ayewo.


Ahmed Iliyasu ti wa ro awon eeyan pe ki won dekun lati maa se idajo lowo ara won, nitori iwa odaran lawon yoo ka si. O so pe, kawon eeyan ma se dekun lati maa fejo awon to ba n dunkoko mo won sun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI