Asiri tawon eeyan ko mo nipa Olusegun Obasanjo Presidential Library - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2017

Asiri tawon eeyan ko mo nipa Olusegun Obasanjo Presidential Library

Ati bi eto ayeye ojo ibi Obasanjo se lo




Tinubu, Osinbajo ati Obasanjo
Bo tile je pe ayeye ogorin odun Aare teleri lorileede Naijiria, Oloye Matthew Olusegun Okikiola Aremu Obasanjo ti waye, o si ti koja lo, bo tile je pe Soosi e, Owu Baptist Church si n palemo lati se ayeye naa lara oto lojo Aiku Sande to m bo, iyen ojo kejila osu yii.

Opo awon otokulu, eeyan jankan-jankan lawujo, ojogbon, Oba Alade atawon oloselu kaakiri orileede Afrika ni won wa nilu Abeokuta tii se olu ilu ipinle Ogun lakoko ayeye naa nibi ti won ti lo anfaani e fi si Olusegun Obasanjo Presidential Library ati Mosalasi kan ninu ogba OOPL naa.

Sugbon nnkan tawon eeyan ko mo nipa OOPL naa po jaburata. Akoko nipe odun 1988 ni Balogun Owu, Oloye Olusegun Obasanjo ti ni ipinu lati ko Presidential Library naa, sugbon ojo kejila osu keta odun 2005 ni won fi kiko e lole.

Eleekeji ni pe, OOPL yii lo je akoko iru e nile Afrika to si je pe ilu Abeokuta tii se ilu abinibi Obasanjo ni won ko si. Bakanna lo si je pe ohun lo dara julo lagbaye gege bi ohun tawon eeyan so.

Ko si eni to wo inu ogba OOPL yii ti ko ni ki aje ku ikale nitoripe owo tabua ni won na sibe nitori ise ti won fee fi se. OOPL ni aaye to fe ti ogba naa si dun wo loju, afefe ogba naa, bi afefe ode orun ni.

Bi ayeye Ogorin odun naa se lo
Ojo Aiku Sannde, ojo kerindinlogbon ni ajo Christian Association of Nigeria, CAN se ayeye naa fun Oloye Olusegun Obasanjo ninu ijo Treasure House of God nilu Abeokuta, nibe naa ni won ti fun un loye tuntun gege bi Asiwaju Onigbagbo nipinle Ogun.

Nibi eto naa lo ti so pe Aanu loun ri gba lowo Olorun Aseda to da oun nitori pe itan igbesi aye oun ko yato si ti Joseph tinu Bibeli bo tile je pe oun ko la ala, sugbon bi irin ajo aye oun se lo, ko seyin oore ofe Olorun toun ri gba.

Nibe lo ti so pe orisirisi isoro ati iponju loun la koja lakoko toun n sin ijoba orileede yi ninu ise ologun ati igba toun di Aare lakoko ologun ati ijoba alagbada, eyi to ye ko mu emi oun lo, sugbon ti Olorun ko je.

O ni pelu irele okan loun fi dupe lowo Olorun nitori pe ipo tawon kan du fun aimoye odun, ti ko bo si won lowo, to si gba emi awon mi in, ni won fi be oun leemeji otooto lati wa se. O so pe ko si oore ofe to to laye.

O tun ni nigba toun je igbakeji Ogagun Shagari to je Aare ologun lorileede Naijiria, opo egbinrin ote lo dide, eyi to ye ko gba emi oun, sugbon to tun je pe se loun tun fi gba igbega lati di Aare ologun lodun 1976.

Obasanjo so pe, oun ko fi Bibeli oun sere, bee loun ko le se lati ma gbadura lojumo kan soso nigba toun fi wa nipo lodun naa lohun.

O tesiwaju pe akoba ni won se foun nigba ti Ogagun Sanni Abacha depo Aare to si ranse pe oun. O ni inu oko oun loun wa ni Ibogun ti Oga Olopaa lorileede yii wa lati wa sope won nilo iranlowo oun, koun wa fun won ni amoran.

O so pe iyalenu lo je pe inu seeli loun ti ba ara oun, eyi toun ko le fi Idi ti won fi ti oun mole mule bo tile je pe won gba pe oun ni opolopo asiri lowo, sugbon ti won ko fe koun fi sita.

Ebora Owu so pe gbogbo eye ati ogbon alumokoroyi ti won gba lati fi gba emi oun ninu seeli naa lo ja si pabo nitori pe ko si ose kan koun ma gba aawe. O ni boun se n gba aawe olojo meta, bee loun n gba olojo meje, ti Olorun si n tu opolopo asiri soun lowo nipase awon ti Olorun gbe dide soun nibe.

O tun so pe awon meta ni won jo ti mole lasiko naa, eyi ti Oloogbe MKO Abiola ati Oloogbe Sheu Yar'Adua ko gbeyin to si je pe awon meji toku ko bo ninu e. O ku ola ki won pa oun ni Olorun gbe Aanu e dide.

Aare ana naa tun so pe leyin toun jade kuro logba ewon, inu oko oun loun pada si, sugbon iyalenu lo tun je nigba toun tun ri awon kan ti won so pe koun wa di Aare Orileede Naijiria. O loun so fun won pe eyi toun se lakoko lo gbe oun de ogba ewon nitori naa oun ko le da si oro Naijiria mo, ki won lo wa elomiran.

Obasanjo nigba to n soro ti omije fee le maa jabo loju e so pe wahala naa po titi, to fi mu oun lo ba awon ore oun, iyen Aare orileede South Africa ana, Oloogbe Nelson Mandela ati Bisoobu Desmond Tutu lati gba amoran won, sugbon won ni anfaani ni yoo je lati se atunse, koun lo se nnkan tawon eeyan n fe.

O so pe pelu adura ati awe ati orisirisi amoran lo je koun gba lati se Aare lodun 1999. Leyin o reyin ni ajo CAN se Obasanjo loso gege bi Asiwaju Onigbagbo Kristeni nipinle Ogun, toun naa si dupe lowo won.

Lojo Aje Monde ni Obasanjo so pe afowofa awon adari lo ko awon omo Naijiria sinu isoro ti won n koju lonii in kii se Olorun lo faa.

Nibi asekagba ayeye ojo ibi ogorin naa ni Olori ijo eleto iyen Methodist tele, Dokita Sunday Mbang ti sapejuwe Oloye Olusegun Obasanjo gege bi aare to dara ju, tawon yooku ko tii ni aseyori to.

Ninu soosi to ko sinu ogba ile ikawe Obasanjo iyen Obasanjo Libray to waye niluu Abeokuta lo ti soro naa.

Ojise Olorun naa lakoko to n se iwasu lori akole to pe ni bi a se le maa fi emi imoore Olorun han. O kan sara si olojoobi naa lori aimoye awon aseyori to ti se laarin akoko to wa nijoba atigba ti ko si nijoba. O wa ro awon asaaju yooku lati fi tie se apeeere.

O ni opo ise ti okunrin ti won n pe ni Ebora owu ti se seyin lo si n wulo di akoko yii lara e ni ti ajo to n gbogun tiwa ibaje to da sile, o ni ko sijoba min in leyin Obasnjo to tun da iru awon nnkan bee sile.

Mbang so pe orile ede yii ko ba ti dara ju bayii loo ka ni awon to sakoso leyin Obasanjo naa ba samulo awon igbese to fi sile paapaa nipa eto ogbin. O so ninu iwasu e pe aare orile ede yii tele je eni toun nife sii daadaa paapaa nigba toun tun gbo pe oun lo maa n dari isin aaro fawon eeyan nigba to wa ni Aso rock.

O wa sapejuwe awon oloselu kan lorile ede yii gege oga (Chameleon) ti oselu ti so di nnkan min in, ti won paro iwa nigba ti nnkan ti won fee te won lowo tan. Ti won tori ife inu won paaro egbe oselu. O ni o ye koju maa gba won ti.

Bakan naa lojo Isegun Tusde to tele ni Oloye Olusegun Obasanjo ko awon ileewe alakobere jo ni Ibogun, ilu abinibi e, nibe lo ti n pa alo fun won, bee lo si tun fawon omoleewe naa lawon iwe to ti se seyin to da lori alo pipa, atawon itan omode.

Sugbon lojo Satide Abameta ijerin niluu Abeokuta gba alejo awon eeyan Pataki Pataki lawujo, lojo naa ni won si ile ikawe nibi ti olori orile ede Liberia Arabinrin Allen Sirleaf Johnson, ati adele aare lorile ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo ti wa sii. Bee naa ni won tun lo akoko ojoobi naa si mosalasi to ko fawon musulumi.

Ni bayii, Oloye Olusegun Obasanjo ti so pe gbogbo nnkan toun da laye yii kii se mi mon on se oun, bi ko se pe oore ofe nikan toun ri gba lati odo Olodumare.


O so pe oun ko mo pe oun si le wa laye titi di akoko yii, nitori aimoye awon nnkan toun ti foju ri ninu aye yii. O wa lo akoko naa lati toro idariji lowo gbogbo awon toun ba ti se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI