Owo te Biola atawon ore e n'Ijebu Igbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 29, 2017

Owo te Biola atawon ore e n'Ijebu Igbo

Lojo Aje Monde ose to koja lowo olopaa ipinle Ogun te awon adigunjale meta ni Ijebu-Ode, ipinle Ogun. Ibi ti won ti lo digunjale lowo palaba won ti segi sawon olopaa lowo.

Biola atawon ore e towo olopaa te
Ohun ti a gbo ni pe Biola Dabiri, eni odun metalelogun; Wasiu Oluyadi, eni odun merinlelogun ati Bolaji Oluwole tojo ori ti e naa je metalelogun ni okete won ko ri aaye boru mo awon olopaa lowo, bo tile je pe won lawon meta toku ti na papa bora.

AWIKONKO gbo pe oro di boolo o yago nigba ti won lawon eeyan naa yawo agbegbe Owakurudu ni garaaji Epe atijo nIjebu Ode ti won si da ibon bole bii eni to n se sinima agbelewo.

Loju ese lawon kan si ti bere sii te awon olopaa to wa nitosi laago lati tete wa doola emi ati dukia awon ara agbegbe naa, kawon adigunjale ma baa ri ise won se.

Ipe naa ni AWIKONKO gbo pe o gbe Oga olopaa, Ogbeni Adebiyi Ademola dide, to si ko awon olopaa e soko lati lo koju won. Sugbon iyalenu lo je pe, won ko tii sokale ninu oko won tawon adigunjale yi ti doju ibon ko won.

Eyi lo mu kawon olopaa naa bere sii yinbon ti won naa. “tako tako, poka, poka” nibon n ro lotun losi, to mu kawon to wa lagbegbe naa sa wole ki won maa baa ba asita ibon pade.

Leyin-o-reyin, won lawon meta na papa bora, towo si te Biola, Wasiu ati Bolaji ko too di pe won ko won lo si tesan won. Loju ese ti iroyin ti te Komisana olopaa, iyen Ahmed Iliyasu leti lo ti so pe oun fee ri oju won ni Eleweran.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe Foonu olowo nla lorisirisi, Ero komputa Laptop meji ati ibon meji ni won ri gba lowo won leyin ti won mu won.

Amo sa, Iliyasu nigba to n fibinu soro lojo naa so pe oun fee ri awon meta toku laipe lati fi won jofin nitori pe kaka ki ewe agbon awon odaran yi de, se lo tun n peleke si. O wa pase pe kawon olopaa FSARS ko won kuro, ki won si ri daju pe won se iwadi lati mu awon to salo naa ki won le tete foju bale ejo.

Bakanna loga olopaa wa ro awon araalu lati ma se dekun lati maa fi oro awon odaran yi to awon olopaa leti nitori pe aabo awon araalu lo je awon olopaa logun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI