Ilu Gudugba ko ni pe e ni Oba titun - Baale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 3, 2017

Ilu Gudugba ko ni pe e ni Oba titun - Baale


Oloye Adekunle Ibikunle to je Baale Gudugba Sangojimi nijoba ibile Ewekoro ipinle Ogun ti so pe ilu naa ti leto lati je Oba nitori pe won ti kun oju osuwon lati ni ade ti won.

Baale soro yii lakoko ayeye odun kan lori ite gege bi Baale ilu naa ati ifinijoye awon oloye tuntun ti won sese yan nilu naa lati maa sakoso ilu pelu Oloye Ibikunle.

Ese ko gbero ni gbagede ti ayeye naa ti waye lojo Abameta Satide, iyen ojo keedogbon osu to koja, nigba ti won fi awon oloye tuntun to to ogoji je nilu Gudugba Sangojimi.

Nibe ni Oloye Adekunle Ibikunle ti so pe inu oun dun lori ona ti ayeye naa gba waye nitori pe ojo nla lo je nilu Gudugba atipe ayeye akoko tawon yoo se nilu tawon eeyan pe jo niyen, opo awon eeyan ni won si ti bere sii kan saara si won pe awon alale wa leyin won.

O so pe bo tile je pe ilu Gudugba ti wa tipe to si je pe Baale ana to waja ko ka iwe, eyi to faa ki owo aago ilosiwaju ilu Gudugba fa seyin die, sugbon ni bayii oriire nla ti wo inu ilu naa wa latigba to ti je Baale nitori pe opo awon omo ilu ti won ti lo ni won ti n pada wa bayi lati wa ko ile silu baba won.

O ni ise ti n lo lori idagbasoke ilu naa nitori pe awon ileese nla nla bii ileese kan to n se oti ti fee bere kiko ileese won, toun si nigbagbo pe laarin odun kan si akoko yii, awon ile ise nla miran tun si n bo.

Baale tesiwaju pe nigba ti yoo ba fi di idayi odun to m bo, ayeye eto igbade lawon yoo maa se, nitori pelu akitiyan lotun losi nipa isokan tawon fi n gbe nilu Gudugba, eyi to mu won se aseyori lori ayeye odun kan ati ifinijoye yi ni yoo mu ki gbogbo ohun ti won ba dawo le yori si rere.

Nigba to n soro lori oro awon Fulani darandaran, o ni awon ko gba won laaye lati huwa buruku nilu Gudugba, nitori pe gbara ti won ti wole lawon ti pe won, tawon si jo so asoyepo ki wahala ma baa sele, kawon si jo maa gbe ni irepo.

Baale Gudugba wa gbawon araalu lamoran pe ki won lo mo daju pe ilu Gudugba ti dotun, kawon to wa lona jinjin rere maa bo lati wa kole silu baba nla won. O ni ko si beeyan se le lo to, ile labo sinmi oko.

O wa kilo fawon oloye tuntun naa pe ki won rii daju pe won n wa sile lasiko to ba ye, nitori pe ko na oun ni nkankan lati gba oye lowo eni ti ko ba kin yoju sile lore-koore.

O ni oloye to ba ko lati wa sile lasiko to ba ye, oun yoo ro loye, toun yoo si gbe oye naa feni to ba wuu, yala Ahusa, Yibo tabi ajoji to ba se tan lati fowosowopo pelu itesiwaju ilu Gudugba.

Ninu oro ti e, Oba Abdul Rasaq Jimoh Famuyiwa to je Onipapa tilu Papalanto nigba to n gbe ade, opa ase ati ileke fawon oloye tuntun naa, o so pe inu oun dun si ona ti ayeye gba waye nitori pe ife ti ko see fenuso ti joba laarin awon eeyan naa.

O ni bo tile je pe ija ti waye seyin laarin oun atawon eeyan naa, sugbon ni bayii, ohun gbogbo lo ti di afiseyin ti eegun n fiso. O wa gba awon oloye tuntun naa lamoran pe ki won rii daju pe won n lo ipo won lati mu idagbasoke ati ilosiwaju ba ilu naa.

Onipapa wa seleri pe oun yoo sa gbogbo ipa ati agbara oun lati rii pe ni idayi odun to m bo, ayeye igbade Oloye Ibikunle gege bi Oba Gudugba loun yoo wa bawon se. Bakanna lo ro awon araalu lati fowosowopo pelu awon oloye tuntun naa, paapaa Baale won.

Okan lara awon oloye tuntun naa, Oloye Ganiyu Adetoyinbo to je Akogun nigba toun naa n soro fi idunnu e han lori oye tuntun naa. O ni bo tile je pe oun ko roo ti tele pe oun yoo je oye nilu Gudugba atipe oye idile oun ni oye naa, sugbon oun ko ni sai dupe lowo Olorun Olodumare fun oore ofe toun ri gba.

O ni gbogbo ona loun gba lati ye oye naa, sugbon won ni dandan afi koun je, nitori pe oye idile awon ni, oun ko si gbodo salai ma je e. O loun ko fi owo ra oye naa. Gege bi ipo oye naa laarin ilu, Oloye Adetoyinbo so pe pelu iwe toun kan, oun yoo ri daju pe oun lo ipo naa lati fir ii daju pe ko si wahala laarin ilu Gudugba.

Otun Baale, Oloye Ogundijo Olalekan lakoko toun naa n ba akoroyin wa soro dupe lowo awon araalu paapaa Baale Gudugba fun anfaani to foun lati wa di ipo naa mu, bo tile je pe oun ko roo ti tele, sugbon sii iyalenu loun fi gba ipe naa.

Lara awon alejo ojo naa ni Oba Abdul Semiu Ogunjobi to je Olorile ti Orile-Ifo; Oloye Abidemi Osunbiyi to je Osi Apomu tilu Owu; Oloye Babajide Adeseun to je Oluwo Apomu. Bakanna ni Ojise Olorun Damilola Shoneye ati Sheik Modupe-Oluwa to je Imam Gudugba ko gbeyin nibe lati fun won ladura.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI