Adeoye be iya agba kan lori l’Abigi nitori oro ile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 3, 2017

Adeoye be iya agba kan lori l’Abigi nitori oro ile


Titi di bi a ti n ko iroyin yin lowo ni odomokunrin kan, eni odun metalelogun, Adeoye Ikugbayigbe fi n so pe ise esu ni, oun ko mo on mo lati pa iya agba eni odun mejilelaadorun naa, iyen Funmilayo Shada. Agbegbe Abigi nijoba ibile Ogun Waterside nisele naa ti waye.

Hassan re o
Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo ketadinlogun osu to koja ni nnkan bi aago mewa aaro ni won ni Adeoye lo ka iya agba naa mo inu igbo to si lo seku pa, nibe lo ti ge ori ati owo e sinu lailoonu to mu dani.

Nibi to ti n lo ni won ni Ekundayo Shada to je okan lara awon omo iya naa ti pade e loju ona, to si beere pe mama oun n ko, sugbon kaka ki Adeoye da lohun, nise lo so eru owo e sile to si sa wonu igbo lati lo farapamo.

Oro naa lo je kayeefi fun Ekundayo. Bo se rii pe Adeoye salo, lo mu ifura dani fun un toun naa si sare wonu oko lati lo wo ibi ti iya e, Funmilayo wa, sugbon nigba ti won ni ko ri iya e, lo ba pada lati lo wo baagi ti Adeoye so sile. Iyalenu lo je fun un pe ori ati owo iya e lo wa ninu e.

“Haa, maami” loro ekun to jabo lenu e, to si fi ibinu naa gba tesan olopaa lo lati lo fejo sun pe Adeoye ti seku pa iya oun, atipe nise lo tun bee lori , to si tun ge owo e.

Ori iya agba naa
Nibi ti won lo ti n soro naa fawon olopaa ni DPO ekun naa, Ogbeni Komolafe Omoniyi ti gbo, to si so pe ko ma soro jinna, lo ba ko soko pelu awon omose bii meloo kan, ti won si gba inu oko naa lo. Eru to gbe sile ni won koko ri, ti won si ri ori ati owo iya naa nibe.

Nigba ti won ri oku iya yii, aanu se won, won si ya foto oku naa fun aridaju. Nibe ni Komolafe ti so fawon eeyan e pe ki won lo wo gbogbo inu oko naa lati wa.

 Ibi to ka si lasiri e ti tu to si n mi bi eni to jabo lori oke. Bi won se ri lo n pariwo pe oun maa jewo, ise esu ni.

Nigba ti won gbe de tesan pelu ada to fi ge iya naa lori lati foro wa lenu wo lo so pe iya naa ko fee foun nile lati fid a oko si, atipe ile naa, oun lo tosi. Adeoye so pe o ti pe tawon ti n fa oro ile naa, sugbon oun ko mo nnkan to ko soun ninu toun fi huwa naa.

Ageku iya agba naa
Gbogbo awon to gbo nipa isele naa ni won so pe oro naa kii se oju lasan, won ni oogun owo ni Adeoye fee fi ori ati owo iya naa se, won ni awon kan lo maa ran nise, ki awon olopaa tubo te ninu daadaa.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro lose to koja so pe nigba ti iroyin naa te oga olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu leti lo ti pase pe ki won maa gbe bo ni Eleweran lati tesiwaju ninu iwadi.

Nigba ti Iliyasu ri odomokunrin Adeoye naa lo ti pase pe kawon olopaa otelemuye bere ise iwadi lori e. Abimbola so pe awon olopaa lo gbe oku iya naa lo si mosuari ti won si ti toju ada ti won gba lowo Adeoye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI