Nitori ojo ibi; Alayo fi orin bu Sefiu Alao l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 5, 2017

Nitori ojo ibi; Alayo fi orin bu Sefiu Alao l'Abeokuta

Ko seni to gbo soro ti won ni Ayoola Akinola Michael topo mo si Alayo fi bu Gbajumo agba olorin Fuji nni, Alaaji Sefiu Alao nitori ayeye ojo ibi e to se ni bonkele nilu Abeokuta, ti ko so pe oro naa ju enu e lo.

Alayo
Ohun ti a gbo nipe l’Ojobo Tosde ose to koja ni won ni Alayo lo sere fun won ni Open Gate to wa ni Abeokuta, nibe lo si ti korin bu Alaaji Sefiu Alao, iyen Baba Oko pe oun le kere loju, sugbon oun dagba sikun nitori naa ko ma foju omo kekere wo oun.

Won ni Alayo so pe ti agba olorin naa ba n se e fawon kan, ko ma se e de odo toun nitori pe oun ti di igi eleera ti ko see gbe dani sere.

Ibinu ni won ni okunrin naa fi korin bu Sefiu Alao lojo naa, sugbon won lawon to wa nibe lojo naa ni won ni ko panumo, ko ma soro seni to juu lo.

Bi won se ni Alayo gboro naa lo tun so pe, bi eni to ju oun lo ko ba fe arifin lodo oun, se ni ki eni naa duro nipo toun ba gbe e si.

Bee lo tun ni ki Sefiu Alao woju o, nitori pe onikaluku lo ni nnkan to gbojule.

AWIKONKO gbo pe, bi okan lara awon to sunmo Alayo se gbo oro yi, lo ti pe e lori foonu lojo keji pe ki lo ri lobe to fi wa iru sowo, to fi je pe Sefiu Alao lo tun n korin bu.

Sefiu Alao
Oun ti won lo o so feni naa nipe Sefiu Alao lo fee maa wo ara e nile, atipe oun ko ni lokan lati korin bu u, sugbon nnkan to se lojo to se ojo ibi e lo bi oun ninu.

Nje kini Alayo so pe Sefiu Alao se foun, o ni lojo to n se ojo ibi loun pe lati ki ku ayeye ojo ibi ni aaro di irole ojo naa, sugbon ko gbe foonu e, ti ko si pe pada lati so pe ki lo sele titi di asiko naa.

Alayo tesiwaju pe kii se igba akoko ti Sefiu Alao maa hu iru iwa bayi soun niyii, o lo o ti n se tipe, sugbon oun ko le muu mora mo nigba ti ko seni toun fee fejo e sun.

Alayo tun so pe oun mo pe toun ba gbe e gba ona koun forin bu, awon to sunmo Sefiu nibi toun ti lo korin yoo mu iroyin naa te lowo, ti yoo si pe oun pada lati bebe.

Ohun tawon to n gbo nipa isele naa ni won n so pe igberaga okunrin ti won pe ni Alayo naa ti poju, atipe ko seni ti ko le soro si.

Titi di bi a ti n koroyin yi, bo tile je pe Sefiu Alao ti gbo nipa isele naa, sugbon ko tii fesi sii. Oun tawon to sunmo Sefiu so nipe, ete ni Alayo n wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI