Adeyinka to lu asewo ni jibiti abe dero orun alakeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 31, 2017

Adeyinka to lu asewo ni jibiti abe dero orun alakeji

Oku Adeyinka
E dakun e se wa jeje lebe tawon asewo meji, Kudirat Raji ti inagije e nje Angela ati Esther Bisiru ti won fesun kan wi pe won seku pa onibara won, Adeyinka Olayinka nitori owo be nigba towo olopaa ipinle Ogun te won.

Gege bi AWIKONKO se gbo oteeli kan ti won poruko e ni KS to wa ni Ifo ni won pa okunrin naa si, eni ti won so pe o wa lati wa sun di aaro ojo keji nitori ile to suu sagbegbe naa.

Ohun ti a gbo ni pe ile kan ti won n ko lowo nilu Ifo ni Adeyinka waa wo nitori pe oun lo n bawon sabojuto e, sugbon nigba tile su, ti ko le pada sibi to ti wa mo, lo ba lo lati lo sun ni oteeli naa.

Nigba to de oteeli KS, lo ba ri awon asewo kan to wa nibe, to si ba Angela duna dura gege bi ise won, tiyen si gba fun. Sugbon oro yi pada laaro ojo keji nigba ti won so pe won deede gbo ariwo awon mejeeji ninu yara ti won sun moju.

Nibi ti won ti n fa oro naa ni won so pe Angela ti ranse pe ore e, Esther pe ko wa a gba oun lowo eni to lu oun ni jibiti abe, ti ko si fee san owo pe foun. Sugbon bi Esther se wole to won ni won so pe o fo igo oti ti won mu mo Adeyinka lori.

Awon asewo mejeeji
Erun igo to ku ni won so pe Angela mu, to si fi gun Adeyinka legbe titi ti awon isan apa e fi ja ko too dipe o subu lule, to si ku fin in-fin. Ariwo ti won lawon osise oteeli naa gbo lo je ki won lo lati lo wo nkan to n sele, sugbon ki won too de be, oku Adeyinka ni won ba nile.

Bi won se fe maa salo lawon to wa nibe sare di won mu pe won ko gbodo lo, ki won too ranse pe manija ti won fi se olori nibe, manija yi ni won lo o ranse sawon olopaa Ifo.

DPO olopaa ekun Ifo, Ogbeni Anthony Haruna lo sare lo lati lo o wo nkan to n sele, nigba to de be lo ba oku Adeyinka nile gbalaja, to si ya foto e ko too di pe won gbe e lo si osibitu jenera to wa ni Ifo.

Lesekese ni won ti ko Angela ati ore e Esther lo si tesan won lati lo foro wa won lenu wo, nibe ni Angela ti so pe Adeyinka ko fee san owo pe foun, to si fe maa lo agbari ti ko ta.

Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe looto ni atipe won ti gbe oku naa lo si motuari fun ayewo finnifinni. Bee lo so pe oga olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won ko Angela ati ore e Esther lo si odo awon olopaa to n ri si oro odaran lati tesiwaju lori oro won.

Iliyasu bu enu ate lu iwa tawon asewo naa hu, o si seleri pe won ko ni pe e foju bale ejo leyin ti iwadi ba pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI