Abimbola Oyeyemi, Alukoro olopaa ipinle Ogun tooto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 31, 2017

Abimbola Oyeyemi, Alukoro olopaa ipinle Ogun tooto

Opo awon araalu lo kominu nigba ti won gbe alukoro olopaa ipinle ogun tele, Omoba Muyiwa Adejobi lo si Zone 2 nipinle Eko, ti won si yan Ogbeni Abimbola Oyeyemi gege bi adele alukoro, nitori ero okan won ni pe ko seni to tun le dabi e laarin awon olopaa mo, iyen eni ti won yoo maa foro lo bi wahala ba sele.

Abimbola Oyeyemi
Leyin osu bii meta ko too di pe won yan alukoro miran lawon eeyan ti n woo pe nibo wa ni eto aabo ipinle Ogun n lo, to si je ki won maa sunku sinu pe emi awon ko de mo, bo tile je pe se lawon odaran da ayeye sile pe aye ti gba awon bayii.

Ko pe sigba naa ni won so adele naa, Ogbeni Abimbola Oyeyemi di alukoro olopaa to si bere ise ti e lekunrere. Oro yi pada laarin osu mefa nigba tawon eeyan bere sii kan saara sii pe ise takun-takun lo n se.

Ni bayii, ko seni meji tawon araalu n dupe lowo e bi ko se Oyeyemi lo, nitori pe o tun je ki ajosepo to dan monran wa laarin awon araalu atawon olopaa kaakiri ipinle Ogun, to je pe ki wahala kan too sele, oun ni won ke si lati ba won yanju e.

Gbogbo Ojoru Wesde ni Abimbola Oyeyemi maa n wa lori eto kan lori redio ti won pe ni Family FM laarin aago mesan si mewaa aaro lati so ibi ti ise aabo de duro, tawon eeyan yoo si so edun okan won fun nipa bawon olopaa kan se n wuwa ti ko bojumu.

Tomode tagba, tonile talejo lo ni ero ibanisoro alukoro Oyeyemi lowo, to si maa n so fun won pe bi won ba ri olopaa kan to n gba riba, tabi to n huwa to n doju ti ise olopaa, ki won fi to oun leti lati fi iya je iru eni bee.

Eyi lo je kawon araalu mo pe looto lawon eeyan rere si wa laarin awon olopaa lorileede yi, paapaa nipinle Ogun. Bi e ba fee mo pe looto loro ti a n so, e lo beere wo lowo awon toro won ti de oluleese olopaa to wa ni Eleweran Abeokuta ri, ki won si so nnkan toju won ri nipa Ogbeni Abimbola Oyeyemi.

Oyeyemi lo n mu ki ise rorun fun Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu, eni to ti jeje pe lasiko toun ba si wa nipinle Ogun gege bi Komisana, oun ko ni faaye sile fun iwa odaran tabi ireje bo ti wu ko kere to. Bee lo si maa n fi kun oro e pe aabo awon araalu lo je oun logun ju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI