Akeko Laspotech to pa ara e, won lo lowo aye ninu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 20, 2017

Akeko Laspotech to pa ara e, won lo lowo aye ninu

Bo tile je pe iyalenu loro Odomobinrin Damilola Adegoke, eni odun mejilelogun to je akeko ile eko giga gbogbonise tilu Eko, iyen LASPOTECH ti won lo o mu oogun apefon (sniper) si n je fawon ebi, ore e, paapaa awon araalu lori igbese to gbe lati gbemi ara e titi di asiko yi.
Damilola Adegoke
Agbegbe Massa nipinle Eko nisele naa ti waye lojo Isegun Tusde to koja.
Ninu iwadi ti AWIKONKO se pelu ohun tawon eeyan n so nipa iku Damilola, ipele kinni lo wa nile eko giga naa nibi to ti n ko eko owo sise ti a mo si Business Administration.

Ohun tawon eeyan n so nipe iku e nipe kii soju lasan, yala boya ko lowo aye ninu tabi ko je pe o wa ninu egbe kan, tawon elegbe e si n so pe asiko to lo laye ti to, ko maa pada bo, sugbon ko seni to le fi aditu to wa nidi iku e mule.

Lojo Aje Monde to koja ni Damilola si ko oro ologbon kan sori ero ayelujara Facebook e pe ki won ma se wo nnkan tawon eeyan n so. See nkan to o mo o se daadaa, maa lepa akosile ti e ki o si fojusona fun ojo iwaju to dara. Eku ose tuntun (“Never mind what others say. Do better yourself, beat your own records every day, and aim for a better tomorrow … Happy new week peeps,”)

Won ni ko fu awon eeyan lara nipa iku e, bo se je pe se lo n sere pelu awon araale, atipe o ti n ba iya e tawon eeyan mo si iya ibeji so awon oro kan to mu ifura dani, sugbon bi iya ibeji ba fee kobi ara sii, se lo maa tun gbe e gba ona miran.

AWIKONKO gbo pe lakoko ti iya e loo serum e lo gbe oogun apefon naa mu, atipe nigba to n bawon oniroyin soro laipe yi lo so pe ara ti n fu oun koun too jade nile, sugbon Damilola lo so foun pe koun tete loo se nnkan toun fee se leekan naa.

O ni ni nnkan bi aago mesan ale toun maa pada de sile loun ri omo oun Damilola nibi to ti n je irora lori beedi, koun too ranse pe awon araale lati ran oun lowo, tawon si gbe e lo si osibitu aladani kan, nibi ti won ti so pe kawon gbe e lo si osibitu ibomiran nitori pe o koja agbara awon.

O so pe oju ona lawon wa to ti dake mo awon lowo. Ninu oro e, o so pe “Awa mejeeji nikan la jo n gbe, ko si sija laarin wa. Ko ba enikeni ja. Laaro ojo yen, buredi ati ata obe la je. To si so pe oun a fi ata toku je indomie losan. O bo sori beedi, o n te foonu e, temi naa si fegbe lele.

“Nigba to ya ni nnkan bi aago kan osan, mo so fun un pe mo fe de odo egbon e lagbegbe First Gate, o so pe ‘Eyo mi le jare.’ O sese bere ede yen laipe yi to pada de lati ileewe ni. Emi ati egbon e si ti beere itunmo ede naa lowo e, sugbon ko so nkan to lodi nipa e.

“Mi o ti e fee jade lojo naa, oun lo ro mi pe ki n lo sibi ti mo fee lo lai mo pe nnkan to fee se ti wa ninu e. O ye ko lo ko omo kan nise ladugbo lojo naa, sugbon nigba ti mo beere lowo e nipa idi ti ko fi lo, se lo jagbe mo mi, ti mo si fi sile.”

“Nigba ti mo maa pada de ile ni nnkan bi aago mesan ale ojo naa, Mo ba nibi to sun si, mo wa ji, bi mo se ji yen, mo wa rii pe ipo agbede meji orun ati aye lo wa. Igba ti mo gboorun enu e, ni mo mo pe oogun apefon lo mu. Lesekese ni mo lo gbe epo pupa ati omi, ti mo si n roo si lenu ki n too pari fawon araale pe ki won gbami.

“Ko le soro mo. Lesekese naa ni won ti so pe ka gbee lo si osibitu ti a si gbee lo si eyi to wa nitosi ile wa. Won so pe o ti ku nigba taa maa debe, a si lo foro naa to awon olopaa leti. Ko si nnkan ifura lori foonu e nigba ti a ye e wo.” Gege bi iya ibeji to je iya Damilola se so.

O tesiwaju pe awon si jo soro ni nnkan bi aago meje koun to dele lojo naa, atipe ipalemo idanwo saa keji lo n se lowo. O lomo oun maa n sere pupo, o si loyaya sawon eeyan paapaa ladugbo. O ti e tun so pe Damilola seleri foun pe oun fee ra iyeri-eti (earrings) foun gege bi ebun ojo ibi oun lojo keta osu kefa to m bo yi.

Okan lara awon ore Damilola, ti won tun jo w anile eko kanna, Faith Omoh nigba toun naa n soro lori iku Damilola, o so pe awon si jo dapara lori foonu ni nnkan bii wakati meji kisele naa too sele. O ni aya oun ja nigba ti mama e pe oun to si salaye pe Damilola mu oogun apefon.

O lawon ko ri nnkan ifura nigba tawon ye foonu e wo. O tun so pe won jo gba awon wole sile eko LASPOTECH lodun to koja ni, idanwo saa keji si ti sunmo etile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI