Asiri Badmus to yinbon pa ore e ti tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Asiri Badmus to yinbon pa ore e ti tu o

O loun ko fe ki asiri tu ni 

Kani Friday Michael, eni odun metadinlogbon ti ore e, Badmus Gbadamosi, eni ogun odun yinbon pa mo pe ibi ti oro naa ma ja si niyen, bo ya ki ba ti tete deyin leyin e, ko si ti salo jinna rere, nitori ti won so pe se lawon mejeeji jo n gbe inu yara kanna ladugbo Mamu nijoba ibile Awa-Ijebu, ipinle Ogun.

Badmus
AWIKONKO gbo pe ni ojo Abameta Satide to koja yi ni Badmus sare wole ni nnkan bi aago mefa aabo aaro, ti ko si roo leemeji, to fi yinbo pa Friday nibi to sun si, nitori awon asiri e ti won loo ti mo nipa awon iwa ibaje (odaran) to n hu laarin ilu.

Won ni o ti le ni odun meji ti won ti jo n gbe, to si je pe won ni okan lara awon ogbologbo odaran ni Badmus je, eni ti won lo ti sekupa opo awon eeyan, to si je pe o tun n jale mo iwa buruku to n hu.

Iro ibon ti won lawon ara ile naa gbo, lo je ki won sare dide lori beedi ti won sun ni, ti won si sare jade sita lati mo nnkan to n sele, sugbon won so pe jijade ti won jade, ni won rii pe inu yara ti Friday ati Badmus n sun ni iro ibon naa ti dun.

Eyi lo mu ki opo won maa beere wipe ki lo sele, ki ni won jo n fa, to fi di pe won n yinbon para won, nitori ti won so pe awon eeyan ko le tete mo pe awon mejeeji kii se omo iya kanna.

Nigba ti Badmus rii pe awon eeyan ti ka oun, lo mu ko fe gbiyanju lati fese fe, ko si na papa bora, sugbon tawon to wa nibe ko je ko ri aaye lati salo, ko too di pe won ranse sawon olopaa Awa-Ijebu.

Lesekese ti won ni DPO Awa-Ijebu naa ti gbo, lo ti teko leti pelu awon isangbe e, ti won si lo lati lo wo nnkan to n sele. Won ni se ni Badmus fee maa bawon olopaa sagidi ko too di pe o gba lati tele won ni tipatipa.

Bo tile je pe orisirisi lawon eeyan ti so fawon olopaa nipa awon ti Badmus n hu, amosa, tesan ni won so pe Badmus ti jewo pe odaran loun, atipe iberu wipe ki Friday ma baa tu asiri oun sita loun se tete pa, nitori ti won lo o so pe kii se eemeji lo ti ka oun nibi toun ti lo jale, oun ko si fe ki asiri oun tu loun see woo pe koun ma fina sori orule sun.

O ni nigba ti Friday ka oun lakoko, oun bee pe ko bo oun lasiri, to si je pe o ni koun seleri wipe oun ko ni jale mo, tawon si jo pari e sibe. sugbon nigba to tun ri oun leekeji lokan oun ko ti bale mo, toun si roo pe o see se ki Friday tu asiri oun sita.

Alukoro ileese olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe awon ti gba ibon to fi pa Friday lowo e, tawon olopaa Awa-Ijebu to lo lojo naa si ti gbe oku Friday lo si mosuari nileewosan kan to wa nitosi fun awon ayawo miran.

O ni Komisana awon, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki awon olopaa digboluja, FSARS tesiwaju nipa sise iwadi to jinle nipa awon ti Badmus jo n sise, ki won si fi won jofin nitori to tun so pe oun ko setan lati gba awon odaran laaye nipinle toun n soju fun.

AWIKONKO gbo pe bo tile je pe Badmus ti jewo awon ti won jo n sise, ati bi won se le ri won mu, Iliyasu so pe aabo ati dukia awon araalu lo se pataki soun nitori oun fe kawon araalu maa sun oorun asundokan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI