Ajo VIO gbe aadota awako lo sile ejo o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Ajo VIO gbe aadota awako lo sile ejo o

Iyalenu loro awon awako aadota to foju bale ejo laipe yi si n je fawon to gbo nipa e, nitori bi won se ni ajo to n ye iwe oko wo, iyen Vehicle Inspection Office, VIO se fi okan-o-jokan esun to nii se pelu lilodi sofin oko kan won nile ejo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, orisirisi okan-o-jokan esun ni won fi kana won awako aadota naa, eyi ti won so pe aini iwe oko lo je koko ninu awon esun ti won fi kan won pelu awon esun to tun lodi si ofin oko ati irinna ko gbeyin ninu esun ti won fi kan won, eyi to mu won jebi gege bi o ti wa ninu iwe ofin ajo naa lorileede yii, to si mu won foju wina ijoba.

Nigba to n AWIKONKO wa soro l’Ojobo Tosde ose to koja, Agbenuso fajo VIO nile kaaro-o-jiire, Ogbeni Taofeek Abimbola Babalola, eni to tun je olori amuseya so pe bo tile je pe ojoojumo lawon fi n pariwo, tawon n parowa fawon awako pe ki won rii daju pe won n iwe oko won n pe ki won too maa gbe oko won soju popona, sugbon eti ikun ni opo won n ko si.

Taofeek Babalola
O lowo ti bawon kan to to aadota tawon si ti gbe won lo sile ejo fun esun otooto to nii se pelu iwe oko, sugbon awon eeyan naa ti n yipada, won si ti n fowosowopo pelu awon.

Abimbola tun soro lori iroyin kan to jade laipe yi pe ijoba ipinle Eko labe Gomina Akinwunmi Ambode fi ofin de ajo VIO fungba die, o so pe bee ko loro ri nitori se ni ijoba n gbero lati gbona min in yo ti yoo je ona igbalode lati maa fi ye iwe oko wo, eyi ti yoo mu nkan rorun fawon fawon osise ajo naa, paapaa awon araalu.

O tesiwaju pe ijoba Eko fee gbe idanilekoo kale fawon osise ajo naa lori bi won se maa n na owo lati fid a moto duro lai je pe won n lo igi, atipe leyin ti ipinle Eko ba ti setan tawon si ri abajade e, lawon yoo too gbawon ipinle to ku lamoran lati bere ti won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI