Awon Fulani tun ti pawon agbe ogun o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Awon Fulani tun ti pawon agbe ogun o

Awon afurasi Fulani agbebon kan ni won ti fesun kan won pe won sekupa awon agbe to to ogun mo inu mosalasi ti won ti n kirun laaro ojo Abameta Satide to koja yi.

awon Fulani darandaran
AWIKONKO gbo pe abule kan ti won pe ni Etogi nipinle Niger ni won nisele naa ti waye, nigba ti won so pe se lawon Fulani naa dabon won bole, ti won si gbogbo awon agbe ogun to n kirun lowo, gege bi Agbenuso awon olopaa ipinle naa, Bala Elkana se so.

Bala tesiwaju pe se lawon odaran naa tun yinbon kaakiri abule naa, ti won si se awon mejo miran lese pelu ibon won.

AWIKONKO ninu iwadi fi han daju pea won Fulani naa ko deede pawon eeyan naa, ohun to faa ni pe se ni won so pe won wa gbesan okan lara won tawon agbe naa pa laipe yii ni.

Gbogbo igbiyanju awon alase lati dawo wahala naa duro ni won lo si n jasi pabo titi ti a fi n koroyin yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI