Nitori igbeyawo, Khadija gbe baba e lo sile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Nitori igbeyawo, Khadija gbe baba e lo sile ejo

Odomobinrin eni odun metalelogun, Khadijat Ibrahim lo ti gbe baba e, Ibrahim Bassa lo siwaju adajo nile ejo agba kan lagbegbe Karu nilu Abuja, nibi to ti fesun kan baba e pe ko je koun fe eni toun nife si gege oko.

Khadija nigba to n soro naa fadajo, lo so pe oun ti ni eni to wu oun lokan lati fe, ti ife awon si ti wo koja oju tenikeni le maa fi wo awon, sugbon se ni baba oun so pe oun ko le fe e.

O ni baba oun ko so idi e ni pato toun ko fi gbodo fe eni toun mu wa fi han an lati se igbeyawo pelu e, sugbon kaka ki baba oun soro, se lo so pe ko seese. O loko afesona oun ti lo gbogbo ogbon e lati ri baba oun nipa eto igbeyawo won, sugbon se ni baba n lo ona alumokoroyi lati yago fokunrin naa.

Khadija ni nnkan ti baba oun n tenumo ni wipe eni toun maa fe kii se Ahusa (Hausa), eyi tii ko si te emi lorun nitori pe eni bi okan oun loun mu wa yen, to si te oun lorun be.

O wa ro ile ejo lati pase fun baba e ko je koun segbeyawo pelu eni toun fe, iyen Asdulhamidu, bo se daruko funle ejo naa.

Nigba toun naa n so tenu e, Baba naa, Bassa so pe ooto lomo oun so, ko si iro ninu awon oro to so kale rara, nitori pe o ni nnkan toun ri, toun fi so be.

O loun ko tii fe ri okunrin to mu wa naa nitori toun ti so fun un laimoye igba pe igbeyawo kii se eremode, atipe ko bawo leeyan yoo se segbeyawo pelu eni tawon ko mo iran e, tabi orirun e.

O ni teeyan ba fee fe eya Fulani, eeyan gbodo mo awon ebi e, nibikibi ti gbogbo won ba wa, ti gbogbo eeyan yoo si mo won pe iru eni bayii ni won n ba lo.

Baba naa wa ro ile ejo lati boju aanu woo un, nitori to so pe omo oun sikere lati mu oko wale, paapaa iru eya to tun lo mu wa lati fe gege bi oko.

Adajo naa, Onidajoo Abdullahi Baba wa gbawon eeyan naa lamoran pe ki won lo ni suuru fun ara won, o si sun ojo igbejo miran si ojo kokandinlogbon osu yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI