Iyawo to ga lo wun mi lati fe - Sanyeri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 24, 2017

Iyawo to ga lo wun mi lati fe - Sanyeri

Oko mi kii soro pupo nile – Iyawo Sanyeri

Omolara ati Olaniyi, Sanyeri
Opo lo maa n woo pe se gbajumo osere tiata aderinposonu nni, Olaniyi Afonja topo mo si Sanyeri le feyawo, ki igbeyawo e tun pe to odun mewa, nitori awon ipa to maa ko ninu fiimu. Sanyeri to ma n sebi eni ti ko dakan mo ninu fiimu, to maa n sebi eni to ponu paapaa to ba debi ka sebi eni gbe obe mu. Sugbon oro ko ri bee nigba ti AWIKONKO se iwadi nipa okunrin yi, ti a si rii pe ogbon yii po ni, atipe gbogbo bo se maa se ninu fiimu yen, ko le se be to ba wa nile.

Sanyeri tawon eeyan tun mo si Opa ti so pe Olorun nikan loun le dupe fun lori igbeyawo oun nitori pe oun ko lero wipe igbeyawo alayo bayii loun le ri gba lowo Aseda. Ninu iforowero yi pelu AWIKONKO, Sanyeri ati iyawo e, Omolara soro, ile kun bi igbeyawo won se pe odun mewa gbako. E ka bo se lo.

AWIKONKO: Nje e si le ranti bi e se pade iyawo yin?
SANYERI : Odun 2004 la pade ni gbongan National Theatre to wa ni Iganmu nilu Eko, nibi ti mo ti safihan sinima mi, Okan Emi ti mo gbe jade nigba naa. Oun naa wa lati lati wa jegbadun ara e ni. Bi mo se ri oun ati ore e kan lookan, mo sunmo ore e yen, mo si so fun un pe mo nife e, ore e yi lo ni kin n lo ba funra mi lati so fun. Bi mo se de odo e, ti mo so fun pe aa wun mi pe ka jo je ore, ka si sunmo ara wa daadaa, nnkan to fi dami loun nipe, se tori emi naa sese ya fiimu temi lo je ki n lero pe emi le fe oun. Bo se kuro niwaju mi niyen. Leyin osu kan si ojo yen, a tun pade nibi kan, ibe ni mo ti gba nomba e, ti a si bere sii soro. Mo sise lopolopo ko to le gba fun mi pe ka jo je ore ololufe, tori a lo opo odun lori e.

AWIKONKO: Ki lo fa okan yin sodo e nigba ti e koko ri?
SANYERI: Awa eeyan maa n ni irufe eni to wu wa lokan lati fi se aya tabi oko. Lati kekere mi ni mo ti pinnu pe eni to ba ga ju mi lo ni mo maa fe, nitori ki awon omo wa naa le ga. Ebun Olorun ti mo ri lara e, pelu bo se singbonle lo koko fa okan mi sodo e. Nigba ti a n fera lo ni mo sakiyesi wipe eeyan daadaa to se e fokan tan ni, oro wa si ye ara wa daadaa, nnkan ti mo ri niyen ti mo si fir ii pe eni to se e fi se aya ni.
OMOLARA: Bo tile je pe o gba mi ni akoko ki n to gba fun nitori ise to n se. O je eni to mo bi a se n toju obinrin, o je eni to se e fokan tan. O loyaya, kii paro, o si n sere pupo.

AWIKONKO: Bawo le se kenu ife si?
SANYERI: Mi o ti e fi oruka kenu ife si nitori pe mi o lowo lowo nigba yen. Mo kan so fun un ni pe mo fe fe sile gege bi aya, mo si lero pe aa pinu lokan ara e boya lati fe mi tabi ko ma fe mi. Nkan to dara nibe nipe o mo mi daadaa, o si gba lati fe mi. Mo ma n sise leyin awon ise amohunmaworan (scenes) ju ti mo si maa n bojuto ina atawon ero ti a fi n ya ise.
OMOLARA: Mo nigbagbo pe Olorun lo ti seto igbeyawo wa lati orun wa. Mo mo pe ko lowo lowo daadaa nigba naa sugbon mo rii gege bi eni ti ojo ola e dara, o si maa n toju mi. eyi lo je ki n fun ni anfaani, sugbon mi o kabamo pe mo fe. Inu mi si dun fun ipo ti a wa loni.

AWIKONKO: Ki lo fun yin ni igboya pe igbeyawo yin le pe bo tile je pe e o tii ri jaje daadaa nigba naa?
SANYERI: Mi o foju tembelu ara mi wipe mi o le se rere laye lojo iwaju. Mo woo pe bi ko ba ti e sowo lowo mi, a ni ife too le gbe wa ro.

AWIKONKO: Oju wo lawon obi yin fi wo oro igbeyawo nigba naa?
OMOLARA: Won kan beere lowo mi pe se eni to wu mi lati fe ni, nigba ti mo si so fun won pe beeni, won fowo si, won si gbaruku ti mi. Won beere awon ibeere to ye ki won beere bii; omo ilu wo ni ati iru idile to ti jade. Won ti e tun beere lowo mi pe se mo nigbagbo wipe ko ni ja mi ju sile to ba di pe o lowo lowo tan lojo iwaju. Leyin-o-reyin sa, inu won dun nitori pe won ri nnkan odi nipa igbeyawo wa.

AWIKONKO: Bawo lo se wa n rorun fun yin lati gbe gege bi loko laya?
SANYERI: Kii se nkan to soro fun mi nitori pe lopo igba lo je pe o maa n te mi lorun ki n maa da wa ninu ile. Ti mi o ba ti ni ibi ti mo fe lo, o maa n te mi lorun ki n wa ninu ile pelu iyawo mi, ki a si tubo jo sere lati mo iwa ara wa daadaa. Koda nigba ti mo di olokiki, mo si n se bi mo n se tele, mi o yi iwa mi pada
OMOLARA: Gege bo se so, o je enikan to feran lati maa wa ninu ile ti ko ba ti ni ise. A n gbiyanju lati mo iwa ara wa paapaa nipa bi idile wa se tubo maa gbooro si nitori pe a ti mo iwa ara wa nigba ti a si n fera gege bi apon ati omidan.

AWIKONKO: Bawo le se le sapejuwe iri igbeyawo yin?
SANYERI: Eni to ba so pe igbeyawo oun n lo geerege, iron la gbaa ni onitohun n pa. Adojuko a wa saa ni. Ni ti wa, a maa n gba fun ara wa ni nitori pe oro wa ti ye ara wa. Iyawo mi maa n to mi sona ti n ba se asise tabi nkan ti ko ba dara, ko ti e ri mi gege bi eni to lokiki. O maa n so pe Niyi loun fe, kii se Sanyeri. Emi naa si maa n to sona toun ba se nkan to ku die kaato.
OMOLARA: Iriri to dara ni. Gege bi a se maa baa pade, a maa n ja, a si maa n pari e laarin ara wa. A o kii gbe oro wa lo sodo eti keta lati ba wa da si, mi o tie nife si rara.

AWIKONKO: Ki ni e le so nipa ara yin?
SANYERI: Iyawo mi feran lati maa lo sawon ode ti won ba ti n pa awon eeyan lerin, nitori o feran lati maa rerin. Nigba miran ti nkan bas u mi tabi ti m ba ti ronu lo, oun lo maa n tu mi ninu to maa bu omi titu simi lokan. O feran lati maa wa pelu awon eeyan, yala agbalagba tabi omo kekere.
OMOLARA: Iwa oko mi yato si nnkan tawon eeyan n ri ninu fiimu agbelewo. Bo tile je pe bawon eeyan ba ti foju kan lerin maa n pa won, sugbon o je eni to feran lati maa da wa nigba miran, ki o baa le ri aaye lati ronu jinle daadaa. Kii se pe gbogbo igba lo maa n rerin ko si maa n soro ju. O maa n toju ebi e, o si maa n rin papo pelu awon eeyan gidi.

AWIKONKO: Bawo le se maa n pari aawo laarin ara yin?
SANYERI: O rorun pupo lati mo iwa eni to ba sunmo yin, ko da bi e ko bai tii gbe ara yin sile gege bi oko atiyawo. Awa eeyan maa n ni akoko ti ori wa maa n wale lati gba oro amoran. Nigba miran, o le je oganjo oru ni maa ji lati so ero okan mi fun. Maa so awon asiri nkan ti ko mo tele fun.
OMOLARA: A maa pari aawo funra wa ni. Ti m ba se, o maa so fun mi, maa si bebe lesekese, oun naa maa n be mi to ba ti se mi. mi o kii ro lemeeji lati so nkan to n je otito fun nitori pe emi ni mo sunmo ju to le se e. mo si maa n ro lati maa so asise mi fun mi dipo ko maa lo so fawon araata. Mi o ri gege bi irawo sugbon gege bi oko mi, mo mo bi mo se le yanju oro pelu e.

AWIKONKO: Nje e le ranti aawo to koko waye gege bi loko laya?
OMOLARA: Ki n ma paro, mi o le ranti nitori pe o ti pe gan. Sibe, ti a ba ni gbonmisi-omioto, a maa n yanju e, a si n ba igbesi aye wa lo.

AWIKONKO: Nje e ni awon oruko ife ti e maa n pe ara yin?
SANYERI: O maa n pe mi ni Ola nitori pe o je agekuru oruko mi, emi naa si maa n pe ni Ola nitori Olaiya loruko oun naa. A maa n pe awon omo wa naa ni Ola, nitori pe nnkan to bere oruko won niyen.

AWIKONKO: Opo igbeyawo ode oni lo je pe won kii pe, ki le ro pe o maa n fa?
SANYERI: Bi igbeyawo yin ba pe, oore-ofe Olorun ni. Eeyan naa gbodo je eni to n gba nkan mora. Igbeyawo ko roru. Bi enikeni ba so eyi to yato si nkan yi, boya iru eni bee n gbe oke-okun ki enikeji e si maa gbe orileede Naijria ni. Sugbon bi won ba n ri ara won lojoojumo, won a maa su ara won. koda, tegbon taburo to n gbe papo gan an n ja.
OMOLARA: Igbeyawo je gbigbe papo pelu eeyan otooto meji ti won ko wa lati ibi kanna. Won a ni orisirisi ona otooto ti won n gba se nnkan, won si gbodo maa ni suuru fun ara won.

AWIKONKO: Kini pataki owo ninu igbeyawo alarinrin?
SANYERI: Owo dara, o si se pataki. Opo igbeyawo to n tuka lo je pe ai le se eto lo n fa. Nigba ti enikan ko ba le se eto to ye, wahala maa wa. Awon okunrin kan wa ti won kii fun iyawo won lowo, sugbon won feran lati ma ate iyawo oniyawo lorun. Mo ka awon eeyan naa si oponu. Mo ti pinu lokan ara mi mo si ti seleri wipe mi o ni fe iyawo oniyawo. Mi o si gbadura pe ki okunrin kan ba mi fe iyawo mi. ti o ba n toju iyawo e, waa ni igboya lati ba soro nigba to ba se nkan ti ko ba dara.
OMOLARA: Owo je gbongbo pataki nkan to gbe igbeyawo duro nitori eeyan a fe te idile  e lorun nipa pipese awon nkan to ba n je idile naa niya. Awon okunrin kan wa to je won kii toju iyawo won sugbon o te won lorun lati na owo yafun-yafun nita. Iyen ko dara to.

AWIKONKO: Bawo lo se maa n ri lara yin ti oko yin ba lo si oko ere ti won si maa lo to ose nibe?
OMOLARA: Mo ti mo ise to n se ki n to fe, ko je nkan tuntun si mi. O maa n je ki n mo irin ese e, o si ti maa n so fun mi ki ojo to n lo too de. Ti ko si ti lo sibi Kankan, o feran lati maa wa pelu ebi nile.

AWIKONKO: Bawo le se n se pelu awon ololufee yin obinrin?
SANYERI: Iyawo mi ko tii ba awon to gba temi ja ri, yala obinrin tabi okunrin ni won. Koda ti a ba lo si oke okun lati lo sise, ti won si maa n so pe ki n fi onte mi sawon ni eya ara, o tie tun maa n gba mi lamoran lati se e fun won. opo won ti e maa n fenukomilenu niwaju e, sugbon ko rii ro. Paapaa tawon omo igboro ba dami duro lati toro owo, o maa n ni ki n fun won.
OMOLARA: Awon ololufe e lo gbe e debi to de loni, o si gbodo ba won se. awon obinrin maa n feran lati ba gbajumo se, ko si si nkan tenikan le se si.

AWIKONKO: Bawo le se n sayeye igbeyawo yin?
SANYERI: Ti a ba wa ni Naijiria, a maa n lo si ile itura ti a si maa n lo ojo meji si meta tabi ose kan. Bi a ba wa loke okun, a maa n lo sawon ibi igbafe lati te ara wa lorun.

AWIKONKO: Iru ounje wo le feran ju?
OMOLARA: Oko mi feran amala, gbegiri ati ewedu, emi feran iresi

AWIKONKO: Ki lawon nkan ti e o le gbagbe ninu igbeyawo yin?
SANYERI: Mi o le gbagbe awon ojo ti ko sowo lowo mi to si maa n duro ti mi. Nigba ti iyawo mi bi akobi omo wa, egberun meta ataabo (#3,500) naira lo wa lowo mi, igba naa le koko. Idi ni yi ti mo fi maa n so pe ko si nkan ti mi o le fun iyawo mi. nigba to maa fe mi, ila ereke mi nikan ni ogun ti mo ni.

AWIKONKO: Nje e maa n ra ebun fun ara yin?
SANYERI: Beeni, kii sii se lawon akoko to ba ye bi ayajo ololufe tabi odun kan. Ti m ba lo si oke-okun, ti mo ri aso to dara, mo maa ra fun iyawo mi. awon aso ti mo si maa n ra fun maa n bamu ju eyi toun funra maa n ra lo. Oun naa maa n ra ebun fun mi.

AWIKONKO: Amoran wo le fee gba awon took taya to sese n dide bo?
SANYERI: A o se ayeye iranti odun igbeyawo wa afigba to pe odun mefa ti a ti n gbe papo gege bi loko laya. Nkan ti mo n gbiyanju lati so ni pe iyawo mi duro ti mi latigba ti mi o ti ni nkankan. Amoran mi fawon obinrin ni pe ki won ma se foju tembelu eni to ba kenu ife si won nitori pe ko lowo lowo. Niwon igba ti eni naa ni ilepa, to si je eni to mo nnkan to n se, gbiyanju e wo, ki o si duro ti. Awon kan wa to je pe won bere pelu owo lowo, sugbon ti won o ni nkankan mo nigba to ya. Ko si nkan to pe lo titi.

Orisun: Punch Newspaper(May 21, 2017)

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI