Iyawo Seun Egbegbe ti bimo tuntun o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 24, 2017

Iyawo Seun Egbegbe ti bimo tuntun o

Ayo abara tintin loro naa bayi ninu idile gbajumo agbefiimu jade nni, Seun Egbegbe nitori pe iyawo e to sese bimo tuntun jojolo.
 
Seun Egbegbe re e
Bo tile je pe Seun Egbegbe si wa latimole awon olopaa to wa ni Kirikiri nilu Eko titi di asiko yi lori esun ole jija ti won fi kan laarin osu meji sira won, to si ti foju bale ejo, sugbon ti ko ri eni to le duro fun leyin ti adajo so pe oun fun ni anfaani pe ki won gba beeli e.

Idi ti ko fi seni to le duro fun Seun Egbegbe nipe, won beru ki okunrin na ma tun lo jale leeketa, toripe leyin ti mu lakoko ti won si gba beeli e, ko ju osu kan aabo lo to tun lo jale miran, eyi lo fat awon eeyan fi sa seyin pe ki Seun ma tun lo doju ti awon.

Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe inu ironu nla lokunrin naa si wa bayii latigba to ti gbo pe iyawo ti bimo obinrin lantilanti.

Onyenike to je okan lara awon orebinrin Seun Egbegbe lo gbe foto omo tuntun naa sori ero ayelujara Instagram laipe yi lati je ki awon eeyan mo pe oun ti bimo tuntun. Inu oyun ni Onyenike wa lakoko  ti won fesun ole jija kan oko e ti pada bimo.

Bi e o ba gbagbe, ojo keta osu to koja, April lo je eleeketa ti Seun Egbegbe foju bale ejo, igba naa lo si ti foju bale ejo gbeyin, sugbon to tun n reti ojo igbejo miran laipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI